Take a fresh look at your lifestyle.

Gbọ́misiomiòtó Ló Ń Ṣẹlẹ Bayii Ni Orílẹ̀-èdè Senegal Báyìí Látàrí Bí Wọ́n Ṣe Sún Ètò Ìdìbò Síwájú

156

Látàrí bi wọ́n ṣe sún eto Ìdìbò Síwájú ni Orílẹ̀-èdè Senegal àwọn ará ìlú n ṣe ìwọ́de èyí tó mú wọn kọlù àwọn ọlọ́pàá ni iwájú ita ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin.

Ìròyìn fi to wa létí wí pé wọn kọ̀wé láti fi kún àkókò Ààrẹ to wà lórí ipo báyìí Macky Sall’s ki wọn sì dáwọ ìdìbò dúrò náà, èyí ló mú wọn sún síwájú nígbà tí o kun ọ̀sẹ̀ mẹ́ta péré ki wọn dìbọ̀.

Khalifa Sall tó jẹ adari fún ẹgbẹ́ òṣèlú míràn ni àwọn ko faramọ ohun tó ṣẹlẹ yìí  nítorí náà ni àwọn ṣe gbè ìgbésẹ ìwọlé lati fi ẹdun ọkan àwọn han wí pé kò dára tó, O ní láìsí àníàní àwọn yóò gba ile ẹjọ lo láti fi ẹdun ọkan àwọn han pẹ̀lú.

Bákannáà Thierno Alassane ti oun naa wa láti ẹgbẹ́ òṣèlú míràn ni àwọn ko ni fi ààyè gba rárá, wí pé àwọn yóò dúró sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin titi àwọn yóò fi ẹ̀ṣìn ti àwọn ń wá.

Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Senegal Sall dáwọ ìdìbò náà dúró fún oṣù mẹfa gbáko.

Lágbayé wọ ọ ri Orílẹ̀-èdè Senegal gẹ̀gẹ̀ bi èyí tó ṣe fi ọkàn tan nípa ètò òṣèlú awarawa, nitori lati ile wa ni ètò ìdìbò won ti n mẹhe.

Comments are closed.

button