Àtúndì Ìbò Ìpínlẹ̀ Ebonyi – Mílíọ̀nù Mẹ́ta Ènìyàn Darapọ̀ Mọ́ Ẹgbẹ́ Òṣèlú APC
Gomina ipinle Ebonyi, ọgbẹni Mr Francis Nwifuru ti fi ìdùnnú rẹ hàn latari bi awọn eniyan se tu jade ni yanturu lati ṣe atilẹyin fún ipolongo ibo fún ọmọ ẹgbẹ APC, Kòfẹ́sọ̀ Anthony Okorie Ani fun ti ìbó atundi ọjọ Abameta to n bọ̀ ni ipinlẹ̀ naa.
Mílíọ̀nù Mẹta ènìyàn ló ti darapọ mọ Ẹgbẹ Oselu APC lati inú ẹgbẹ oṣelu yoku.
Nwifuru sọ pé inú òun dùn láti ri pe awọn eniyan wa lati inú ẹgbẹ oṣelu yoku lati wa dara pò mọ́ egbé òsèlú wọn.
” Ìjọba wa ni, gbogbo wa níláti sa ipá wa láti jẹ́ kó tẹ̀ẹ́ síwájú.”
Gomina náà sọ pe oun gbagbọ pé ẹgbẹ oselu APC ni yóò bóri ni ọjọ Abameta.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san