Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ yógun jà – Aṣojú Palestine bẹbẹ

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

263

Aṣojú Palestine sí Nàìjíríà, Abdullah Muhammad Shawesh, ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí gbogbo àgbáyé àti àwọn onínú ire ènìyàn láti ri pé ogun Gaza wá sí òpin lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Nigba ti o n ba awọn oniroyin sọrọ ni Eko nibi iba awọn onirouin sọrọ pẹlu atilẹyin igbimọ to ga julọ to n mojuto ọrọ ẹsin isilaamu, NSICA,Aṣoju naa sọ pe, bi ọmọ eniyan ṣe n daamu ati pipa ọpọ eniyan ni  Gaza ti n pọju ti o si fa ki o beere pe kilode ti eniyan ko ni aanu eniyan ẹgbẹ rẹ loju.

O bẹnu atẹ lu ọmọ ogun alaabo ni Israeli (IDF), fun bi iku awọn eniyan ṣe n pọ si, ipadanu ara, ati wahala ironu to n lọ lọwọ ni Gaza lojoojumọ.

O sọ pe ero IDF ati Adari Israeli ni lati pa Palestine run ki o si gbẹsẹ le ilẹ wọn lati fẹ agbegbe Israel loju to ba ya. Ti wọn ba ṣe afihan nọmba lati 1917 si 2023, Aṣoju Muhammad Shawesh ṣalaye pe ida mejidin-lọgọrin ninu ida ọgọrun ilẹ Palestine ni wọn gba ni 1967, pẹlu Golian Heights, ti IDF si pa awọn eniyan nipa kupa titi di oṣu kinni 2024.

Comments are closed.

button