Ibùsọ̀ ọkọ̀ ìlúmọ̀ọ́ká ti Area 1, ní Garki, Olú ìlú Nàìjíríà, Abuja ti fa ìṣàkóso àti ìṣiṣẹ́ ibùsọ̀ ọkọ̀ lé ẹgbẹ́ onímọ́tò lọ́wọ́.
Adari iṣẹ, ti iṣakoso ise lilọ bibibọ oju ọna, DRTS, Deborah Osho, sọ eleyi lasiko gbale gbana ibusọ ọkọ ni ỌJọọru ní Area 1, Garki, Abuja.
Osho bẹnu atẹ lu bi iṣakoso FCT, ṣe gbale gbata ibusọ mọto naa ni ọsẹ to kọja, ti o wa jẹ pe ṣe ni awọn janduku ati awọn iṣe ti ko bofinmu tun pada sibẹ, leyi ti o mu ki wọn tun pada lọ tun gba fun igba miiran.
O wa sọ pe, “Wọn gbọdọ maa lo ibusọ ọkọ naa fun iṣẹ gbigbe lọ bọ, wọn ko gbudọ fi silẹ ki awọn mọto ti ko tọna ati awọn janduku maa wa gbere gbere kaakiri.”
Awọn oṣiṣẹ DRTS ṣalaye pe iṣe naa, leyi ti wọn yoo ṣe ní gbogbo awọn ibusọ ọkọ ni Abuja, yoo ṣe iranlọwọ idena gbigbe mọto soju ọna kaakiri.
Igbakeji aarẹ, Ẹgbẹ osiṣẹ onimọto oju ọna ni Naijiria, Dokita Abubakar Sadiq, ti o gba ibusọ mọto naa lorikọ awọn ti wọn n siṣẹ nibẹ, pinnu lati lo ibusọ naa bi ijọba ṣe fi ilana silẹ.