Mínísítà ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ nígbà kan rí gba oríyìn fún ìyípadà tó dé bá àwọn ìlànà
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Mínísítà Nàìjíríà fún ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àti Ọrọ̀-Ajé orí Ayélujára nígbà kan rí , Ọ̀jọ̀gbọ́n Isa Ali Pantami, ti gba oríyìn fún ipa adarí àti ìṣèdásílẹ̀ àwọn ìlànà lórí ìdàgbàsókè ayélujára orílẹ̀-èdè.
Awọn gomina ipinlẹ Borno, Ọjọgbọn Babagana Zulum, Ipinlẹ Gombe, Yahaya Inuwa ati ti Nasarawa, Sule Abdullahi, ti wọn ṣe igboriyin yii, fi idi ipa ti Pantami ko ni agbegbe Imọ Ẹrọ Iṣalaye ati ibaraẹnisọrọ (ICT), ati lilo awọn ohun elo ayelujara lati yanju awọn ipeninija ti n koju orilẹ-ede mulẹ.
Gbogbo wọn sọrọ nibi ifilọlẹ ati iṣagbekalẹ fun gbogbogboo iwe kan ni Abuja “A Scholar’s Journey Navigating the Academia,” ti Ọjọgbọn Pantami kọ.


Iwe naa sọrọ nipa irin ajo rẹ lenu iṣẹ ijọba ati ikopa rẹ lori ikọni, si ICT ati Ọrọ-Aje ori Ayelujara.

Gomina Ọjọgbọn Babagana Zulum ti o jẹ alaga ayẹyẹ naa sọ pe awọn ilana ti o wa latọwọ Pantami gẹgẹ bi Minisita fun eto ibaraẹnisọrọ ati ọrọ Aje ori ayelujara nipasẹ idasilẹ ati kiko awọn ohun elo ayelujara ni fifi gbọ ti awọn ipeninija ode oni ati ti o si tun wa rọ ijọba to wa lori oye lati tẹ siwaju lori ere rẹ.
