Take a fresh look at your lifestyle.

Ìpèsè Omi Tó Mọ́ Gaara: Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Pe Fún Ìrànlọ́wọ́ Àjọ ‘Water Aid International’

174

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti pe fún ìrànlọ́wọ́ pàtàkì lati ọ̀dọ̀ ilé iṣẹ́ kan tí kìí ṣe ti ìjọba, ‘Water Aid International’ láti se àgbédìde ẹ̀ka tó n mójú tó ìpèsè omi tó mọ́ gaara.

Gẹ́gẹ́ bi atejade ti Kọmísánnà fún Ìròyìn, Dọtun Oyelade fi ṣọwọ́ sí àwọn oníròyìn ti ṣàlàyé pé ẹni tíì ṣe Alága ilé iṣẹ́ tó n pèsè omi ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Elias Adeojo ṣé àbẹ̀wò sí ìlé iṣẹ́ tó n pọn ọtí ní ìlú Ìbàdàn (Nigerian Breweries Ltd, Ibadan,NBC), ni ọ̀nà àti pé fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Àjọ ‘Water Aid International’ fún ìpèsè omi tó mó gaara fún àwọn olùgbé Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Adeojo nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ kó di mímọ̀ pé ti ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ bá lè rí ìrànlọ́wọ́ ti wọn pè fún, yóò jẹ kó rọrùn fún ìjọba láti pèsè omi fún àwọn agbègbè tí kò ní omi tó mọ́ gaara, yóò sì tún la ọ̀nà fún ìgbé ayé ìmọ́tótó ọlọ́jọ́ pípẹ́.

Adeojo tún tẹnu mọ́ pé, ìhà ti ijoba ba kọ si ìgbàyègbádùn àwọn olùgbé Ìpínlẹ̀ rẹ ni yóò jẹ́ ọ̀pá kùtẹ̀lẹ̀ láti jẹ́ kó rí ìrànwọ́ owó tó tó Ẹgbẹ̀rún lọ́nà Ọgọ́rùn-ùn Euros gbà láti ọ̀dọ̀ Àjọ ‘Water Aids International”, nígbà tó fi kún àlàyé rẹ̀ pé, Àjọ náà wà láti ṣe iranlọwọ fún iṣẹ́ àkànṣe ìpèsè omi, ìmọ́tótó àti ọ̀pá omi ni àwọn Orilẹ èdè Áfíríkà.

Adeojo tẹ̀ síwájú nígbà tó fi kún àlàyé rẹ̀ pé, ìpèsè omi jẹ́ ojúṣe ìjọba sí àwọn ènìyàn rẹ lai sí ìrètí èrè kankan. O wá fi àsìkò àbẹ̀wò náà rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn Alamojuto ilé iṣé NBC láti dìde ìrànlọ́wọ́ ni ònà àti ri owó ìrànwọ́ náà gbà.

Ṣáájú ni Ọga ilé iṣẹ́ NBC, Ṣeun Akinwale ti lu Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́,Seyi Makinde lọgọ ẹnu fún ìṣèjọba rẹ̀, o wá fi àsìkò náà ṣèlérí pé òun yóò máa bá ile iṣẹ NBC sọrọ lórí ìpèsè omi tó mó gaara fún àwọn olùgbé Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Abiola Olowe
Ìbàdàn.

Comments are closed.

button