Take a fresh look at your lifestyle.

Ìṣẹ̀lẹ̀ Ìbúgbàmù Nílùú Ìbàdàn: Olúbàdàn Kẹ́dùn Pẹ̀lú Àwọn Tó Lùgbàdì Ìjàmbá

196

Olúbàdàn Ilẹ̀ Ìbàdàn Ìbàdàn, Ọba Lekan Balogun, Allí Okunmade II ti ṣe àbẹ̀wò sí àgbègbè tí ìbúgbàmù àwọn ohun èlò ìwakùsà ti ṣe ìjàmbá fún ọpọlọpọ èèyàn, nígbà tí àìmọye náà pàdánù ẹ̀mí wọn, tó sì gbàdúrà kí Ọlọrun tẹ gbogbo wọn sáfẹ́fẹ́ ire.

ỌtunBalogun Ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Tajudeen Ajíbólá to ṣe àbẹ̀wò náà lórúkọ Oba àlàyé náà ló ba ìdílé àwọn tó padànu ẹ̀mí wọn kẹ́dùn, nígbà tó gbàdúrà fún àwọn tó farapa ati awọn ti pàdánù ohun ìní wọn sì ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Bákan náà ni Oba Ajibola pẹ̀lú àwọn Ọba míràn àti olóyè tún lọ ṣe àbẹ̀wò sí ilé ẹ̀kọ́ṣẹ́ ìṣègùn òyìnbó UCH (University College Hospital) láti lọ gbàdúrà fún àwọn tó n gba ìtọ́jú látari ìjàmbá náà.

Lara àwọn ti Ìgbìmọ̀ Olúbàdàn tun ṣe àbẹ̀wò sí ní, ilé Ashipa Balogun, Ọba Kolawole Adegbola, ilé ẹni to ti fi ìgbà kan ri jẹ́ igbákejì Gómìnà ní Ìpínlẹ̀ Òyó, oloye Iyiola Oládòkun àti ilé ẹni to ti fi igba kan rí jẹ igbákejì Akojanu ni ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àgbà, Aṣòfin Hoṣea Agboola ti àwọn náà Lùgbàdì ìṣẹ̀lẹ̀ náà

Ni gbogbo ibi ti Oba Ajibola ṣe àbẹwò sí náà ló ti jisẹ Olúbàdàn ilẹ Ìbàdàn to sì jẹ kó di mímọ̀ pé Oba Balógun ba wọn kẹ́dùn ni irú àsìkò yii tó sì gbàdúrà kí Ọlọrun fi òpin sí irú ìṣẹ̀lẹ̀ bayii.

 

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Comments are closed.

button