Take a fresh look at your lifestyle.

Ilẹ̀ Rírí Oníwakùsà Pa Méjìlélógún Ní Orílẹ̀-èdè Tanzania

145

 

Èjìlélógún ènìyàn ló ti gbẹ̀kọ je lọwọ ẹbọra látàrí ìwakùsà aláìbófinmu tó fa ilẹ̀ ríri tó wáyé ní agbègbè Àríwá Tanzania, àwọn aláṣẹ sọ èyí.

Iṣẹlẹ náà wáyé ní ibi iwakusa Ng’alita ni agbegbe Bariadi, eka Simiyu. ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, Komisọ́nà agbegbe,Simon Simalenga sọ èyí.

Ó sẹlẹ̀ pé, àwọn ènìyàn kan bẹrẹ sí ní n wa kùsà ni agbegbe ti ijọba ti fi ofin de látàrí òjò tó lágbára ki ìṣèlẹ̀ láabi náà tó ṣẹlẹ̀.

Ààrẹ Samia Suluhu Hassan kẹ́dùn gidigidi fún àjálù náà.

Ọ̀gbẹ́ni Simalenga sọ pé ènìyàn mọ́kàndínlógún sí ogún ní wọn tile kọkọ sọ pé wọn lugbadi ọran náà, sugbon paríparí rẹ wọ́n kó òkú eniyan
Méjìlélógún jáde.

Wọn ti fi ofin lélẹ̀ ki àwọn ènìyàn mayse dé agbègbè náà latari ojo arorodá to ti fa ọpọlọpọ ikùn omi.

Àilemójútó àti ìwakùsà ni àìbófinmu a máa wáyé púpọ̀ ni orílẹ̀-èdè Tanzania tó jẹ́ olùpèse Góòlù tó pọ̀ jùlọ ní àgbáyé.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button