Ilẹ̀ gẹẹsì fẹ fi ikọ̀ ọmọ ogun, ogun ẹgbẹ̀rún ranṣẹ sí ilé alawọ funfun gẹgẹ bí iṣẹ àjọ NATO ni abala akọkọ odun yi, pẹlú ọkọ ogun oju omi, bàálù ogun ti òfurufú, ẹka eto ààbò sọ eyi ni ọjọ Ajé.
Ni ara ifiranṣẹ náà la tun ti ri Mẹ́rìndínlógún ẹgbẹ̀run ọmọ ogun ilẹ gẹẹsi ti won yóò dúró sí àgbègbè ila oòrùn Yúrópù lati oṣù Kejì sí ìkẹfà, ọkọ òfurufú akérò àti ti F35B Ikọlu oníná àti àwọn ọkọ ofurufyu asèwádìí.
Àjọ NATO ti fi kún atilẹyin wọn leyin ààrẹ Vladimir Putin ti kéde Ikolu sí orílẹ̀-èdè Ukraine bí ọdún méjì sẹyìn bayìí, nípa ìrànwọ́ ọmọ ogun, orọ̀ ajé, ati igbayegbadun omo ènìyàn fún Kyiv.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san