Ìjọba Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Sí Ilé Agbára Iná Mọ̀nà-mọ́ná,Tí Ó Sì Di Lílò Ní Ìpínlẹ̀ Niger
Ìjọba àpapọ̀ ti sí iná mọ̀nà-mọ́ná èyí tí ó ń lo agbára òòrùn ní ìlú Kainji, ìpínlẹ̀ Niger, ààrin gbìngbìn Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
Àkànse isẹ́ náà wà lára ìgbésẹ̀ ààrẹ Tinubu láti mú ìgbòòrò bá ìpèsè iná fún àwọn olùsòwò àti fún àmúlò mùtú-mùwà
Mínísítà fún ọ̀rọ̀ agbára iná, Adebayọ Adelabu sàlàyé nígbà tí ó ń sọ ohun èlò náà di lílò wípé, ìgbésẹ̀ náà yóò mú àlékún bá ìpèsè iná tí àdíkù yóò sì bá owó iná ní sísan.