Ìjọba Àpapọ̀ Àti Ìpínlẹ Kebbi Ti Parí Ètò Láti Mú Ìgbòòrò Bá Ètò Ọ̀gbìn Èyí Tí Yóò Mú Àdíkù Bá Ọ̀wọ́ngógó Oúnjẹ
Ìjọba àpapọ̀ àti Ìpínlẹ̀ Kebbi ti gbé ìgbésẹ̀ akin láti mú ìgbòòrò bá ètò ọ̀gbìn èyí tí yóò mú àdíkù bà ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ, tí oúnjẹ yóò sì wà lọ́pọ̀ yanturu
Mínísítà Fún Ètò Ọ̀gbìn àti Ìpèsè Oúnjẹ, Sẹ́nétọ̀ Abubakar Kyari àti gómìnà ìpínlẹ̀ Kebbi, Mohammed Idris ni wọ́n jùmọ̀ sọ ọ̀rọ̀ náà nígbà tí Idris se àbẹ̀wò sí mínísítà ní ọjọ́ Ẹtì, ní ìlú Abuja
Ó fi àrídájú hàn sí mínísítà pé, ijọba ipinlẹ Kebbi ti parí ètò láti mú àlékún bá ọ̀gbìn àlìkámọ̀ lábẹ́ ètò ọ̀gbìn ìjọba àpapọ̀
Kyari wá sàpèjúwe ìpínlẹ̀ Kebbi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ìpínlẹ tí ó mú ètò ọ̀gbìn alábomirin ní ọ̀kúkúdùn.