Take a fresh look at your lifestyle.

Makinde Yan Olùdámọ̀ràn Pataki Láti Ṣojú Ẹkùn Ìjọba Àpapọ̀ Àti Alága Ìgbìmọ̀ Ìrìn-àjò Hajj

164

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti bú ọwọ́ lù ìyànsípò Dare Adeleke gẹ́gẹ́ bíi Olùdámọ̀ràn pàtàkì tí yóò máa ṣojú Ẹkùn Ìjọba Àpapọ̀, nígbà tó yan Alhaji Hashim Atere gẹ́gẹ́ bíi Alága Ìrìn-àjò Hajj ní Ìpínlẹ̀ Òyó.

Gẹ́gẹ́ bi àtẹ̀jáde tí Olórí oṣiṣẹ fún Gómìnà, Segun Ogunwuyi fi ọwọ́ sí, àwọn tí Gómìnà yàn gẹ́gẹ́ bíi amugbalegbee àti àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tí yóò ti máa ṣojú fún ẹkun ìjọba àpapọ̀ náà ni:

1. Ayo Fatokun – Ìjọba Ìbílẹ̀ Akinyele/Lagelu

2. Alani Alwajud – Ìjọba Ìbílẹ̀ Oorelope/Irepo/Olorunsogo

3. Julian Nwachukwu – Ìjọba Ìbílẹ̀ Àríwá Ìbàdàn

4. Alhaji Labule Ishola Olasupo – Ìjọba Ìbílẹ̀ Àríwá Ìwọ̀ Oòrùn/Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn Ìbàdàn

5. Akinajo – Ìjọba Ìbílẹ̀ Àríwá Ìlà Oòrùn/Gúsù Ìlà Oòrùn Ibàdàn

6. Olumide Akinlade – Ìjọba Ìbílẹ̀ Oluyole

7. Hezekiah Sanjo Akintola – Ìjọba Ibilẹ Ogo-oluwa/Surulere

8. Kamorudeen Kayode Obisesan – Ìjọba Ìbílẹ̀ Egbeda/Ona-Ara

9. Hakeem Adedibu – Ìjọba Ìbílẹ̀ Iseyin, Itesiwaju, Kajola & Iwajowa

10. Alhaji Monsuru Oduola – Ìjọba Ìbílẹ̀ Àríwá/Ààrin gbùngbùn Ibarapa

11. Matthew Kayode Akano – Ìjọba Ìbílẹ̀ Ìlà Oòrùn Ido/Ìlà Oòrùn Ibarapa

12. Waheed Oluwakemi – Ìjọba Ìbílẹ̀ Ìlà Oòrùn/Iwọ Oòrùn Saki, Atisbo

13. Alawode Liasu – Ẹkùn Oyo

14. Abileko Toyin Olaniran – Ìjọba Ibilẹ Ariwa/Gúsù Ogbomoso, Oriire.

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Ìgbìmọ̀ Ìrìn-àjò Hajj ni Ipinlẹ Òyó ni:

1. Alhaji Abdulrasheed Olokuta – Igbákejì Alága

2. Alhaji Dauda Badmus Ọmọ ẹgbẹ́

3. Imaamu Mojeed Lanase – Ọmọ ẹgbẹ́

4. Gani Laaro – Ọmọ ẹgbẹ́

5. Alhaji Jimoh Sijuade Amodu – Ọmọ ẹgbẹ́

6. Alhaji Olayiwola Bizimilahi – Ọmọ ẹgbẹ́

7. Alhaja Oyegbori Fatimah – Ọmọ ẹgbẹ́

8. Alhaji Razak Ayoola Mustapha – Ọmọ ẹgbẹ́.

Gómìnà wá gba gbogbo wọn níyànjú láti rí ìyànsípò wọn gẹ́gẹ́ bíi ìpè láti ṣiṣẹ́.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Comments are closed.

button