Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti rawọ ẹbẹ sí àwọn adari ilé ìjósìn Kristiẹni kan to ba ilé ẹ̀kọ́ Alakọbẹrẹ St. Paul, ni agbègbè Odo-Ona ni ìlú Ìbàdàn láti dẹ́kun lilo ilẹ̀ ilé ẹkọ náà fún ibojì òkú.
Ẹni tíì ṣe alága Àjọ to n rí sí ìpèsè ẹkọ kárí ayé ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ (Oyo State Universal Basi Education Board, SUBEB) Ọmọwe Nureni Adeniran ló sọ èyí di mímọ̀ lásìkò tó lọ ṣe ibẹwo sí àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tó wọlé fún sáà kejì ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Ọmọwe Adeniran àti àwọn ikò to lo ṣe ibẹwo náà jẹ́ kó di mímọ̀ pé, yàtọ̀ sí pé ilé ìjósìn náà gba lára ilẹ ilé ẹ̀kọ́ St. Paul, o tún lo ilẹ̀ náà láti máa sin òkú sí. O wá fi yé ilé ìjósìn náà pé Àjọ ti oun jẹ́ alága rẹ̀ kò fara mọ́ irú ìgbésẹ bẹ ẹ nitori pé o lodi sí òfin.
Nigba to n sọrọ, ọkan lára àwọn olori ni agbègbè ilé ẹkọ St. Paul, Julius Oguns jẹ́ kó di mímọ̀ pé, kii ṣe orúkọ ile ijọsin lo wà lórí ilẹ náà ṣugbọn orúko ile ẹ̀kọ́ St. Paul. O wá ké sí ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti dá sí ọtrọ̀ náà nítorí àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà fi oju ri awọn ohun ti kò lẹtọ fún wọn láti máa rí ní ayika yara ikawe.
Adeniran wa fi àsìkò náà pá laṣẹ fún akowe eto ẹ̀kọ́ fún ìjọba ìbílẹ̀ Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn Ìbàdàn,Abileko Morenike Adeniran àti awọn oṣiṣẹ (UBED) to wà ní ijoba Ìbílẹ̀ náà láti ṣe ìpàdé pẹ̀lú olórí ìjọ náà.

Bákan náà ni Adeniran tẹnu mọ fún àwọn olórí ile ẹkọ ni aarin gbùngbùn ilu Ìbàdàn tó sì rán won leti pe ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti sọ fún wọn láti rí dájú pe àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ wọlé lásìkò ti ìjọba ti la kalẹ.
O wa fi ìdùnnú rẹ̀ hàn sí àwọn olùkọ́ to wà ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ tí o ṣe àbẹwò sí fún bí wọ́n ṣe tẹ̀lé ìlànà, tó sì tún fi àsìkò náà rawọ ẹbẹ sí àwọn òbí àti alágbàtọ́ lati yọnda àwọn ọmọ wọn nítorí pé iṣẹ́ ikẹkọ ti bẹ̀rẹ̀.
Lara àwọn ilé ẹ̀kọ́ tí wọn ṣe ibẹwo sí ní, St. Paul to wa ni agbègbè Gada-Apata, Odo-Ona, Ìbàdàn; Christ the King Catholic School, Odo-Ona; Community Model Basic School, Elewura; St. John School 1&2, Aremo; Methodist Basic School I&II, Agodi, Ìbàdàn.
Abiola Olowe
Ibàdàn