Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹnikẹni Tó Bá Tapa Si Òfin Àyíká Yóò San Ẹgbẹ̀rún Mẹ́wàá Náírà Owó Ìtanràn

169

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti kéde rẹ̀ pé ìjìyà wà fún gbogbo ẹni tó bá tápà sí òfin tó ní ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àyíká láti san ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá naira (N10,000) tàbí kó fi oṣù kan gbáko ṣe iṣẹ́ àgbègbè.

Kọmísánnà fún ọ̀rọ̀ àyíká àti ohun Alumọni ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Abdulmojeed Mogbonjubola ló sọ ọ̀rọ̀ yìí lásìkò ti ọwọ́ sìnkún òfin ilé iṣẹ́ náà tẹ àwọn mokandinlogun (19) to tápà sí òfin náà ni agbègbè Alakia àti Iwo-Road ni ìlú Ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Mogbonjubola jẹ́ kó di mímọ̀ pé àwon ikọ̀ amúṣẹ́yá ti ilé iṣẹ́ náà yóò bẹ̀rẹ̀ sí máa paraaro tìbú-tòòró Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lọsẹsẹ títí sisan ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá owó ìtanràn yóò fi fìdí múlẹ̀.

O tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kò ní fi ààyè gba dída idọti káàkiri láàrin ìlú mọ́.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ, Mogbonjubola ni: “O jẹ ẹsẹ nla láti da idọti sí àárín ojú òpópónà ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́”

Nígbà tó n fi ìmọ riri àwọn èèyàn rere Ipinle Oyo hàn fún bí wọ́n ṣe tẹle òfin agbegbe eléyìí tó mú kí Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ wà ní imototo tó sì dùn wò lójú, Kọmísánnà fi àsìkò naa kéde wí pé Ìjọba kò ní tẹti nínú ṣíṣe ojúṣe rẹ̀ láti mú kí àyíká àti agbègbè Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ dùn ún gbé fún àwọn èèyàn àti àwọn oludokowo.

Abiola Olowe
Ibàdàn

Comments are closed.

button