Ìjọba Orílè-èdè olominira Congo ti kéde Ìlú Ò fararọ látàrí òjò àrọ̀rọ̀dá
tó ti n rọ̀ ni nǹkan bi oṣù kan ó lé.
Owó pàjáwìrì tó ju mílíọ̀nù mẹ́rin dọ́là ni ìjọba orílẹ̀-èdè náà ti gbekalẹ fún ìrànwọ́ àwọn tó lùgbàdì ọ̀ràn náà àti láti ṣe àtúnṣe sí àwọn nǹkan to ti bàjẹ́ ní ẹlẹ́ka jẹ̀ka. Inú àwọn ènìyàn sí ti dùn sí èyí, sùgbọ́n wọ́n fẹ́ ìgbésẹ̀ kíákíá.
Abúlé tó dín ní irinwó àti agbègbè merindinlọ́gbọ̀n ni omiyale náà ti ṣẹlẹ, ẹgbẹ̀rún lọnà odunrun o le ogun eniyan lo sí ti fara gba nínú iṣẹlẹ naa.
Mẹ́tàdínlógún ènìyàn ti jỌ́lọ̀run nípè, mẹ́fà di àwárìí, àwọn elétò àmójútó àyíká ti pe fún ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ gbogbo eniyan
Ìròyìn ròó pé àwọn ènìyàn ń gbìyànjú láti dẹ́kun ìṣẹ̀lẹ̀ náà sugbọn kòsí ìrètí pé òjò yóò dá lẹ́yìn oṣù péréte bí àwọn tó mọ ojú ọjọ́ se sọ.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san