Take a fresh look at your lifestyle.

Adari Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Anambra Ki Àwọn Ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Kú Ayẹyẹ ọdún Tuntun

189

Adarí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Anambra, Somtochukwu Udeze tí fí da àwọn ènìyàn Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lójú pàápàá jùlọ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Anambra wí pé nínú ọdún tuntun yìí , wọn yóò gbádùn òfin àti ìdájọ tí kò ní àbùkù.

Nínú ọ̀rọ̀ ìkíni ayẹyẹ ọdún tuntun ti Emma Madu tó jẹ akọwe fún Adarí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin buwọ́lù ni ọ̀rọ̀ náà tí jáde.

Ó gbàdúrà fún àlàáfíà àti ìlọsíwájú fún gbogbo ènìyàn Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ó ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ẹlẹ́kẹ̀ẹ́jọ labẹ ìjọba Gómìnà Soludo, yóò gbìyànjú láti rí wí pé ohun gbogbo lo wà ní abé ofin ati ètò.

Ó ní ìdàgbàsókè,ati irẹpọ yóò wà láàrin àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Anambra.

Ó wà rọ àwọn ènìyàn láti Fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọba ìpínlẹ̀ Anambra, ó pé àwọn lọ́balọ́ba, awọn eto ìsìn láti má gbàdúrà fún àlàáfíà ìpínlẹ̀ náà.

Comments are closed.

button