Ààrẹ Burundi, Evariste Ndayishimiye, ti pé fún ìsọlókúta pa àwọn Igbeyawo ako sí ako ati abo sí abò pe èèwọ̀ ni ati pe o burú jáì, ó fi ìdí ti ẹ̀sìn fi lòdì si hàn.
Ààrẹ náà tile ti pe tele pe kí asa náà kò kógbá wọlé ki wọn sì rí gege bí ọmọ ale ti ko ní ìran.
Ó korò oju sí orílẹ̀-èdè aláwọ̀ funfun ti won ko fe ètò LGBTQ+, o sì pé awon to n fe asa náà bí ti alawọ funfun, kí wọn kuku duro sí òkè òkun. O tile di mímọ pé awọn orilẹ-ede kan ni agbaye tilẹ ma n so irufe awon eniyan bẹẹ sí ewon.
Èdè aiyede kan bé sílè nipa ẹ̀tọ́ LGBTQ+ awọn eniyan ti olori ijo Pope Francis fi sọ pé ìbùkún wá ninu fifẹ okunrin si okunrin ati fífẹ obinrin sí obinrin ti awọn kan sí lòdì sí kaakiri agbaye.
Eleyi mu iyipada wa ninu eto ati ilana ijo katoliki kárí ayé, sibe ijo kristi ni apapọ lòdì sí , wọn sì wà lórí ẹsẹ wọn atijọ pé kò yẹ. Ijo kátólìkì ni apapọ náà kò ti gba wole. Láti fi asa búburú náà lèlẹ̀ kariaye ko lee rọgbọ bi wọn ṣe sọ.
Ọ̀pọ̀ ìjọ onìgbàgbọ́ ni ilẹ̀ Adúláwọ̀ lòdì sí. Fún àpeere, orílẹ̀-èdè Togo àti àwọn Bísọ́ọ̀bù orile-ede Cameroon sọ pé àwọn kò fẹ, wọ́n korò ojú sí ìlànà náà.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san.