Take a fresh look at your lifestyle.

Mínísítà ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ túnbọ̀ fìdí àtìlẹyìn ìjọba múlẹ̀ lórí òmìnira àwọn oníròyìn

Eyitayó Fauziat Oyetunji

184

Mínísítà Naijiria fun ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ati Iṣalaye, Mohammed Idris, ti túnbọ̀ fìdí àtìlẹyìn ìjọba múlẹ̀ lórí òmìnira àwọn oníròyìn ni Naijiria.

Nigba ti o n sọrọ nibi abẹwo awọn osisẹ lati ile iṣẹ awọn akọroyin Kariaye ikọ ti Naijiria (IPI) ni ọfiisi rẹ ni Abuja, Minisita naa wa ṣalaye pataki ojuṣe akọroyin ni orilẹ-ede.

 “Aarẹ tiwantiwa ni eleyi, ti o si nigbagbọ ninu ilana ominira akọroyin.

Aarẹ Tinubu jẹ ẹni ti o nifẹ ominira akọroyin gẹgẹ bi tiwantiwa, ti o ja fitafita fun ifaaye gba ijọba tiwantiwa ni Naijiria ,” Minisita naa sọ bayii fun ọpọ eniyan to pejọ si ọfiisi rẹ.

Aṣoju IPI, ti alakoso agba ti Times Nigeria ati aarẹ ikọ Naijiria ti IPI, dari wa gboriyin fun minisita naa bi oṣe lo iriri rẹ nidi iṣẹ ikọroyin lori ipo rẹ bi Minisita fun eto ibaraenisọrọ.

Aṣoju naa tun wa rọọ lati ri pe atunṣe n ba ominira akọroyin ni Naijiria.

Inu wa dun pe ọkan lara wa ni o jẹ minisita fun eto ibaraenisọrọ.

A mọ pe o le ṣee nitori pe kii ṣe pe o ti siṣẹ nikan lori ikọroyin, o nifẹ ominira ikọroyin.O nifẹẹ ominira akọroyin,” Mojeed sọ bayii.

Lori iroyin ti ko fidi mulẹ, minisita wa rọ awọn oniroyin lati gba iwaju lori kikoju iwa aburu naa gẹgẹ bi awọn ẹni to niiṣe pataki.

 

Comments are closed.

button