Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ S’eyi Makinde àti Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Ademola Adeleke ti ṣèlérí láti fọwọ́sowọ́pọ̀ fún ìṣọ̀kan ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ni Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn..
Nígbà tó n sọrọ lórí ìdí pàtàkì tó fi ṣe ibẹwo sí Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Adeleke jẹ́ kó di mímọ̀ fun àwọn oníròyìn lẹyin ìpàdé wọn tó wáyé ni yàrá ìgbàlejò tó wà ní ilé iṣẹ Ìjọba ni Agodi ni ìlú Ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ni Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà, pé oun lu Makinde lọgọ ẹnu lórí iṣẹ́ tó n ṣe ni ẹka ìpèsè ohun amáyédẹrùn, to si fi àsìkò náà ṣèlérí láti pawọ́ pọ̀ fún ìṣọ̀kan àti ìlọsíwájú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ni Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn.
Makinde, ẹni tó se àpèjúwe Adeleke gẹgẹ bíi arákùnrin rẹ̀ náà ló mímọ̀ pé ọ̀nà láti mú kí iṣọkan ati ilosiwaju dé bá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ni Ẹkùn yìí ni ìpàdé wọn dá lé lórí, tó sì tún tẹnu mọ pé àwọn yóò ṣe ohun tó lẹtọ láti ṣe.
Bákan náà ni Gómìnà Adélékè fi àsìkò náà sọ fi mímọ̀ pé òun yóò gbiyanju láti tọ ipasẹ Gómìnà Makinde láti ìpèsè ohun amáyédẹrùn ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, tó sì fi kún àlàyé rẹ̀ pé òun àti Gómìnà Makinde ti fẹnu ọ̀rọ̀ kò lórí ìlọsíwájú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.
Ṣáájú, nígbà tí n ba àwọn ìgbìmọ̀ aláṣẹ Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ sọrọ, Adeleke ṣàlàyé pé idi ti Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti Ọ̀ṣun ṣe ni àkọsílẹ ìlọsíwájú ni pé, òun àti Makindé jẹ́ ọrẹ ti ìmọ̀ wọn sì papọ̀.
O wá fi àsìkò náà gbà gbogbo wọn níyànjú láti túbọ̀ máa fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Gómìnà Makinde nítorí oun ri wí pé o n ṣe takun-takun ni ẹka ìpèsè ohun amáyédẹrùn.
Abiola Olowe
Ìbàdàn