Ìsúná 2024: Agbẹnusọ fún igbákejì adarí ilé ìgbìmọ̀ gbóríyìn fún àjọṣepọ̀ tó wà láàrin Aláṣẹ Aṣòfin
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ilé ìgbìmọ̀ Aṣojú ẹlẹ́ẹ̀kẹwàá lẹ́ẹ̀kansíi fihàn pé òhun yàtọ̀ sí àwọn tókù pẹ̀lú àjọṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ikọ̀ aláṣẹ àti ṣíṣètò ìwé owó Ìsúná 2024.
Igbakeji Adari ile, Aṣofin Philip Agbese, sọ eleyi di mimọ nigba ti o n fesi si ifojuhan aarẹ Tinubu ní ipade apapọ ile igbimọ
O sọ pe , ilé ìgbìmọ̀ Aṣojú ẹlẹ́ẹ̀kẹwàá, labẹ iṣakoso Aṣoju Tajudeen Abass ti ṣafihan itara ti ko lafiwe fun awọn ọmọ Naijiria ati ifẹ fun ijọba rere.
O sọ pe bi adari ile ṣe n yanju awọn ọran to jẹmọ igbe aye irọrun awọn ara ilu jẹ ki oun ni ifẹ awọn toku oun ati awọn ọmọ Naijiria lapapọ,

Aṣofin Agbese tun wa ṣalaye pe labẹ iṣakoso Aṣoju Abbas, ile igbimọ gbe igbesẹ kiakia lori afikun iwe ofin owo nina nitori bi gbogbo nnkan ṣe le lorilẹ-ede ti wọn ko si gbagbe abala to nilo iyanju bii ariyanjiyan ọkọ oju omi.

O ni yatọ si tẹlẹ ti ile igbimọ mejeeji yoo maa ba ara wọn ja ati ba ara wọn sọ ọrọ kobakungbe lori Isuna, eto naa lọ nirọwọ irọsẹ pelu ododo.
Leave a Reply