Gòmìnà Ìpínlẹ̀ Cross River, Bassey Otu ti parí ètò láti mú ìgbòòrò bá ìgbòkè-gbodò ọkọ̀ òfurufú, nígbà tí ó gba ilé iṣẹ́ Aero láyè lati bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ìlú Calabar
Gómìnà Otu tún gbé ìgbésẹ̀ láti mú àlékún bá ọkọ̀ òfurufú èyí tí a mọ̀ sí Cally láti méjì sí márùn-ún
Ọ̀kan nínú àwọn ọkọ̀ òfurufú tí ìpínlẹ̀ náà rà (Boeing 737-5N BYR) ti gúnlẹ̀ sí pápákọ̀ òfurufú ti àgbáyé Margaret Ekpo tí Gómìnà sì se ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀, èyí tí ìrètí wà pé yóò mú ìrọ̀rún bá síṣe ìrìnàjò lọ sí ìlú Èkó àti Abuja.
Leave a Reply