Take a fresh look at your lifestyle.

Ààbò: Ọba aládé gbóríyìn fún gómìnà Adamawa

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 153

Ọba aládé kan ní ìpínlẹ̀ Adamawa, (Hama Bachama), Dókítà Daniel Shaga ti gbóríyìn fún gómìnà ìpínlẹ̀ náà, Ahmadu Fintiri fún akitiyan rẹ̀ láti fìdí ààbò múlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ náà.

Hama Bachama ti o tun jẹ alaga fun igbimọ ibilẹ tun fifi ẹ mulẹ pe ailaabo jẹ ifasẹyin pataki fun isẹ ọgbin ati eto ọgbin, idagbasoke amayedẹrun pataki, ẹkọ, irin ajo afẹ ati ibaraẹniṣepọ- ọrọ aje ni Naijiria.

Dokita Shaga sọ eleyi di mimọ ni aafin rẹ ni Numan, ipinlẹ Adamawa , Ariwa ila oorun Naijiria, nigba ti o gbalejo awọn ero olukopa mejidin-logoji  ninu iṣẹ mejile-lọgbọn,  ti ile iwe giga ti aabo lorile-ede , NDC, ti wọn wa ni ilu naa fun irin ajo ikekọ.

O wa sọ fun awọn alejo naa wipe ti ti di asiko yii, ipinlẹ naa, paapaa julọ agbgbe Gusu ati ni pato apapọ agbegbe Numan ti aafin rẹ wa ti ri idaamu orisiriṣi ipeninija aabo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button