Take a fresh look at your lifestyle.

Àjọ EFCC Fí Ojú Ọmọ Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga Mọ́kànlá Ba Ilé Ẹjọ́ Fún Ẹ̀sùn Jìbìtì Orí Ẹ̀rọ Ayélujára

0 180

Àjọ EFCC, Ẹkùn Ìbàdàn ti fi ojú àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga Obafemi Awolowo ni Ile-Ifẹ Mọ́kànlá ba ilé ẹjọ́ látàrí ẹ̀sùn jibiti orí ẹ̀rọ ayélujára tí àjọ náà fi kan wọn.

Àwọn Mọ́kànlá yìí tíì ṣe ara àwọn afurasí oníjìbìtì orí ẹ̀rọ ayélujára Mọ́kándínláàdọ́rin (69) to kò sí panpẹ Àjọ EFCC ni ọjọ́ kínní oṣù yìí ni agbègbè Oduduwa Estate ni Ilé-Ifẹ, ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun náà ni Àjọ náà ti kó wá láti jẹ́jọ́ níwájú Onídàájọ́ Nathaniel Ayo-Emmanuel ti ilé ẹjọ́ gíga jùlọ tó wà ní ilu Òṣogbo tíì ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ni Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà.

Àwọn olùjẹ́jọ́ Mọ́kànlá náà ní: Perekebena Olombeni Micah, Nnekwelugo Nnaemeka, Moyosore Favour Oluwasakin, Aghwaritoma Wisdom Obaro, Daniel Olashile Maiye, Gbolahan Khalid Adesina, Yinka Temitope Jayeola, Olumuyiwa Emmanuel Adeleye, Abiola Emmanuel Oluwadare, Busari Abdulazeez Ayodeji àti Okesipe Tobiloba Paul.

Nígbà tí ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú mẹsan wọn n jẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn ẹyọ kan, àwọn méjì tó kù, Micah àti Obaro n jẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn mẹfa ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Nígbà tí ilé ẹjọ́ sọ pé Perekebona Olombeni Micah fi ara rẹ̀ pé ohun ti kò jẹ, bi o ṣe pé ara rẹ̀ ni obìnrin pelu oruko ‘Pies’ ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà lati lù àwọn èèyàn ilẹ Améríkà ni jibiti, ẹ̀sùn eléyìí tó tako abala kejì ìwé òfin Jibiti orí ẹ̀rọ ayélujára tí ọdún 2015 (Section 22 (2) (b) (i)) pẹ̀lú ìjìyà rẹ̀ nínú abala ìwé òfin kan náà.

Bákan náà ni ile ẹjọ́ sọ pe Aghwaritoma Wisdom Obaro náà fi ara rẹ̀ pé oyinbo alawọ funfun pẹ̀lú orúkọ ‘Alex Stephens’ ọmọ ilẹ Améríkà fún Megan Johnson ni ọna àti lu jibiti, ẹ̀sùn eléyìí tó tako abala kejì iwe òfin Jibiti orí ẹ̀rọ ayélujára tí ọdún 2015 (Section 22 (2) (b) (i)) pẹ̀lú ìjìyà rẹ̀ ninu abala ìwé òfin kan náà.

Ṣùgbọ́n awọn olùjẹ́jọ́ méjèèjì ni àwọn kò jẹ̀bi ẹ̀sùn ti ilé ẹjọ́ fi kàn wọ́n.

Agbẹjọ́rò fún olùpẹ́jọ́, Oluwatoyin Owodunni rọ ilé ẹjọ́ láti fi àwọn olùjẹ́jọ́ naa pamọ́ sí ọgbà Atúnniṣe (Correctional Centre) titi di ọjọ́ ìgbẹ́jọ́ wọn.

Agbẹjọ́rò àwọn olùjẹ́jọ́ wọnyii: Ayodeji, Adesina, Oluwasakin, Micah, Adeleye ati Okesipe ṣàlàyé pé òun ti fi to ilé ẹjọ́ létí láti gba oniduro àwọn olùjẹ́jọ́ náà, tó sì rọ ilé ẹjọ́ láti gba ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, nínú èyí tí Onídàájọ Ayo-Emmanuel fara mọ́ọ kí ilé ẹjọ́ gba oniduro àwọn olùjẹ́jọ́ mẹfa náà.

Nígbà tí ilé ẹjọ́ ni kí ẹni kọọkan nínú Ayodeji, Adesina, Oluwasakin, Adeleye àti Okesipe san owó tó tó Mílíọ̀nù Méjì Náírà (N2,000,000.00), ki Micah sì san Mílíọ̀nù Mẹta Náírà (N3,000,000.00),

Tabi ki àwọn olùjẹ́jọ́ náà mu oniduro meji ti tó iye owó tí ilé ẹjọ́ ni kí wọn san, nínú èyí tí oniduro kínní gbọdọ̀ jẹ́ bàbá tabi iya rẹ̀, nígbà tí oniduro keji gbọdọ̀ jẹ́ mọlẹbi, ẹ̀gbọ́n tabi àbúrò, òjíṣẹ Ọlọ́run tàbí òṣìṣẹ́ ìjọba, ti wọn sì gbọdọ búra sí àlàyé ti won ba kọ sílẹ̀ nipa ara wọn, iṣẹ́ ati ilé ti wọn ngbé níwájú Akọ̀wé ilé ẹjọ́.

Onídàájọ́ sun ìgbẹ́jọ́ sí ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù Kọkànlá ati ọjọ Kejìlá oṣù Kejìlá ọdún 2023, nígbà tí wọn taari àwọn olùjẹ́jọ́ náà sì ọgbà atúnniṣe to wa ni ìlú Iléṣà ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.

Abiola Olowe
Ìbàdàn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button