Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Asòfin Èkó ṣe àtúnṣe sí Òfin Ètò Ìṣúná-owó ọdún 2023

OLARENWAJU LAGADA ABAYOMI

0 416

Ile Igbimọ Asofin Ipinlẹ Eko labẹ Oludari Ile, Aṣofin Mudashiru Ọbasa ti ṣe atunṣe si Ofin Eto Iṣuna-owo ọdun 2023 fun Ipinlẹ Eko, eleyii ti o faaye gba ṣiṣe atunto fun inawo Biliọnu lọna mọkan-le-lọta-le-ẹẹdẹgbẹrin ati miliọnu lọna igba-le-mejidinlogun ati ẹgbẹrun lọna marun-din-lọta-le-irinwo ati arun-din-lọgọta owo naira (#761,218,455,055).

Ṣiṣe atunto si inawo yii lo nii ṣe pẹlu lẹta ti Gomina Babajide Sanwo-Olu ti Ipinlẹ Eko fi ṣowọ si Ile Aṣofin naa, to fi beere fun ṣiṣe atunṣe si Eto Iṣuna-owo ọdun 2023.

Ninu ipade ijiroro Ile Aṣofin yii lọjọ Iṣegun (Tuesday) ni Alaga Igbimọ Fun Eto Ọrọ-Aje ati Iṣuna-owo Ilu ninu Ile Aṣofin naa, Aṣofin Lukmoh Olumoh ṣe agbaekalẹ abajade ati imọran igbimọ naa lori igbesẹ yii, ibẹ ni awọn ọmọ ẹgbẹ ti fi ọwọ si i gẹgẹ bi ipinnu Ile.

Ninu ipade ijiroro Ile Aṣofin naa, ti Igbakeji Oludari Ile, Aṣofin Mojisọla Meranda dari, awọn aṣofin naa ka abadofin yii ni igba kẹta, ki wọn to gba a wọle.

Abadofin naa ti wọn pe akọle rẹ ni: “Abadofin fun Ṣiṣe Atunṣe si Eto Iṣuna-owo ọdun 2023 ati fifun wọn laṣẹ lati ṣe Atunto si inawo Biliọnu lọna mọkan-le-lọta-le-ẹẹdẹgbẹrin ati miliọnu lọna igba-le-mejidinlogun ati ẹgbẹrun lọna marun-din-lọ̣ta-le-irinwo ati arun-din-lọgọta owo naira (#761,218,455,055) lati inu apo gbogboogbo owo ilu fun Inawo Atigbadegba, ati Tiriliọnu kan ati Bilọnu mẹfa ati Miliọnu lọna marun-din-lẹgbẹrin ati ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin ati ọgbọn-le-nigba owo naira (#1,006,795,700,230) lati ara Owo iṣẹ Idagbasoke ilu fun Inawo Iṣẹ-akanṣe”, eyi ti gbogbo ọmọ ẹgbẹ Ile Aṣofin naa fẹnu ko fọwọ si.

Lẹyin eyi ni Igbakeji Oludari Ile Aṣofin naa sọ fun Akọwe-agba Ile Aṣofin yii, Amofin Olalekan Ọnafẹkọ lati fi ẹ̀dà ifẹnuko naa ṣọwọ si awọn ibi to ba yẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button