Take a fresh look at your lifestyle.

Mínísítà tẹnumọ́ ìpinnu ìdàgbàsókè ọ̀dọ́

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 175

Mínístà fún ìdàgbàsókè àwọn ọ̀dọ́, Dókítà Jamila Ibrahim ti tẹnumọ́ ìpinnu rẹ̀ láti gbọ́ ti àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà.

Minisita naa sọ pe oun ni ifẹ awọn ọdọ ti ọrọ awọn ọdọ si tun wa lookan aya oun.

Minisita ṣe idaniloju yii nigba ti o gba awọn agba oṣiṣẹ igbimọ aṣofin ti awọn ọdọ Naijiria, (NYP), ti adari igbimọ naa, Azeezat Yishawu, ṣadari lalejo, ní Abuja, olu-ilu.

Minisita wa gboriyin fun adari naa fun amojuto igbimọ naa ti o si n mu da wọn loju pe oun yoo wa wọrọkọ fi ṣada lori ipeninija NYP, ati pipese iranlọwọ to ṣe pataki.

Dokita Ibrahim wa pinnu pe oun yoo ṣe aṣaro lori ijabọ apejọ aabo awọn ọdọ lorile-ede, ti o si fi kun un pe ọrọ ọdọ ati awọn obinrin jẹ oun logun. O sọ bayii pe, Ti o ba di ọrọ ọdọ ati awọn obinrin, ohun ti mo gbadun pupọ ni, paapaa julọ riran wọn lọwọ nitori pe mo ri wọn gẹgẹ bi araa mi.” 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button