Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde tí ké sí gbogbo èèyàn Ìpínlẹ̀ náà láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Ìjọba láti mú kí àyíká àti agbègbè jákèjádò Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ le rẹwà ni ìbámu pẹ̀lú àlàkalẹ̀ “Gbé ìgbésẹ Ara Rẹ” (Own Your Action) ti Ilé iṣẹ tó n rí sí ọ̀rọ̀ Àyíká àti Ohun Alumọni se agbátẹru rẹ̀.
Makinde lo sọ ọ̀rọ̀ yìí níbi ìpàdé àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn to wáyé ni ìlú Ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà, pẹlú àkòrí tó sọ pé “Ẹ jẹ ká Fọwọ́sowọ́pọ̀”.
Gẹ́gẹ́ bí àlàyé rẹ̀, Gómìnà ní, àyíká to mọ kìí ṣe láti lè mú kí agbègbè tó rẹwà nikan ṣùgbọ́n o ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ìlera ara tó yá àti bí igbe ayé ẹni ṣe ṣe pàtàkì tó”
O wá fi àsìkò náà tẹ mọ gbogbo àwọn tó péjú síbi ìpàde náà létí pé wọ́n ní láti jẹ́ ki ìmọ́tótó di bárakú nínú ìwà àti ìṣe wọn, nígbà tó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, dídá ìdọ̀tí káàkiri le ṣe okùnfà ìtànkálẹ̀ àrùn.
Bakan náà ni Gómìnà koro ojú sí dídá ìdọ̀tí káàkiri ìta gbangba, nígbà tó jẹ kó di mímọ̀ pé kó bù ẹwà kún Ìpínlè Ọ̀yọ́ àti wí pé o jẹ́ ohun tó lè fa ìdíwọ́ fún ìlera gbogboògbò.
Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ, Kọmísánnà fún ọ̀rọ̀ Àyíká àti Ohun Alumọni, Abdulmojeed Mogbonjubola náà fi àsìkò náà gbà gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn níyànjú láti mú kí Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ wà láìsí ìdọ̀tí kò sí rẹwà.
Bákan náà, nígbà tó n fi àsìkò náà ké sí gbogbo olùgbé ati ọmọ bíbí Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ pe wọn ni láti kọ ìhà to dára sí mímú kí àyíká wọn wa laini idọti, ni pàtàkì jùlọ, nipa sise amojuto idọti, ìmọ́tótó ati àwọn ohun míràn tó jọ mọ́ àyíká ẹni. O wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, irúfẹ́ ìgbésẹ tí wọn bá gbé lónìí ni yóò jẹ́ ọ̀pákùtẹ̀lẹ̀ fún ọjọ ọla rere.
O tun fi àsìkò náà rán wọn létí pé, àlàkalẹ̀ Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fún Ìdàgbàsóke ọlọ́jọ́ pípẹ́ ni láti mú kí àyíká àti agbègbè jákèjádò Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ rẹwà, nígbà tó sọ fún wọn pé ijiya ti wa fún ẹni yòówù tó bá tápà sí òfin ìmọ́tótó rọ mọ ìmọ́tótó.
Abiola Olowe
Ìbàdàn
Leave a Reply