Ni ìgbáradì láti dènà ẹ̀kún omi, Ìjọba Ìpínlè Ọ̀yọ́ ti fẹ ojú àwọn odò nlánlá àti kekeeke mẹjọ jákèjádò àwọn ẹkùn ní Ìpínlè Ọ̀yọ́.
Kọmísánnà fún Ọ̀rọ̀ Àyíká àti Ohun Alumọni, Ayàwòrán ilé Abdulmojeed Mogbonjubola, ẹni tí Olùdarí ilé iṣé Ìjọba náà, Oladiipo Mukaila sójú fún lo lewaju ikọ ìjọba láti mọ ibí tí iṣẹ́ dé dúró lórí àwọn odò náà tí ìjọba wòye pé o ṣeéṣe kó kún kọjá bebe rẹ̀.

Àwọn odò nlánlá àti keekeke náà ni Ẹkùn Ìbàràpá ni: Odò Araromi; Odò Boroboro; Odò Osunwon ni ìlú Oyo; Odò Ọra/Lala ni ìlú Ogbomoṣo; Odo Jalugbe ni ìlú Ìlerò; Odo Telebu-Ayin-Opaleki ni Igboora.
Àwọn yòókù ní agbègbè Oke-Ogun ni: Odò Ọgba ni ìlú Iseyin; Odò Koba, ni òpópónà Ogboro ni ìlú Ṣakí; àti Odò Fedomu ni ìlú Igbeti.
Kọmísánnà wá jẹ́ kó di mímọ̀ pé ìjọba gùn lé ìgbésẹ fífẹ ojú àwọn odò yìí látàrí àsọtẹ́lẹ̀ tí Àjọ to ni ṣe pẹ̀lú ọrọ omi ni Orilẹ èdè Nàìjíríà, NIHSA (Nigeria Hydrological Service Agency) àti Àjo to n wòye bi ojú ọjọ́ ṣe rí, NIMET (Nigerian Meteorological Agency) ti sọ nípa àwọn Ìpínlẹ̀ ti yóò lùgbàdì ẹ̀kún omi ni ọdún yìí, nínú èyí tí Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ jẹ ọkan.

Lára àwọn ikọ tó lọ wo ìbi ti iṣẹ́ dé dúró náà ní, òṣìṣẹ́ láti ilé iṣẹ́ Ìjọba to n rí sí Ọrọ Àyíká, ilé iṣẹ́ Ayẹwo owó wò ati ẹ̀ka to n pèsè ohun èlò gbogboogbo (Auditor-General and Public Procurement).
Abiola Olowe
Ìbàdàn
Leave a Reply