Gómìnà Ìpínlẹ̀ àwọn ọmọ jẹ lógún, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ jáde láti gbárùkù ti Ìjọba ni ọ̀nà àti mú ayípadà dé bá ètò ẹ̀kọ́.
Makinde lo sọ ọ̀rọ̀ yìí ní ile ẹ̀kọ́ Government College Ìbàdàn (GCI) tó wà ní agbègbè Àpáta ni Ilú Ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà, lásìkò tó lọ ṣí àwọn ohun èlò eré ìdárayá tí ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ jáde (Government College Ìbàdàn Old Boys Association, GCIOBA) pèsè fún ìlò àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà.
Gómìnà wá fi àsìkò náà ṣàlàyé pé, ìṣèjọba òun yóò túbọ̀ máa gbé ètò ẹ̀kọ́ lárugẹ, nígbà tó ṣèlérí pé Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yóò ma tẹ síwájú láti kún GCIOBA lọwọ láti mú kí ògo ilé ẹ̀kọ́ náà padà bọ sípò.
Gómìnà Makinde, lẹ́yìn to sí àwọn ohun èlò eré ìdárayá, fi àsìkò ọ̀hún dupẹ lọwọ àwọn GCIOBA fún akitiyan wọn lórí ilé ẹ̀kọ́ náà láti ìgbà to ti n tukọ ìṣèjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, o sì rán wọn létí pé Ìjọba nikan ko le kojú gbogbo ìpèníjà ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́. O wá rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí wọn láti fi ọwọ́ sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Ìjọba láti jẹ́ kí ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́ gòkè àgbà.
Gómìnà fi kún ọ̀rọ̀ nígbà tó fi hàn pé, owó tó tó ọgọta sí àádọ́rin Bílíọ̀nù Náírà ni owó tí ìjọba nilo láti ṣe àgbédìde àwọn ohun amáyédẹrùn ni ẹka ètò ẹ̀kọ́ ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Lára àwọn ohun èlò eré ìdárayá tí àwọn GCIOBA pèsè ní ibi ìgbá bọ́ọ̀lù aláfọwọ́jù sínú ajọ̀, (Basket ball court); bọ́ọ̀lù eleyin (volley ball); àti bọ́ọ̀lù aláfọwọ́-gba (handball), yàrá ìkàwé (library), àti yara ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọwọ méjì (technical education workshops for wood and metal works), eléyìí tí CBN se àtìlẹ́yìn fún ìpèsè rẹ̀.
Lára àwọn tó kọwọ rìn pẹ̀lú Gómìnà ní igbákejì Alága ẹgbẹ́ Òṣèlú PDP ní Ẹkùn Gúsù, Taofeek Arapaja; àwọn Kọmísánnà ilé iṣẹ́ Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti àwọn èèkàn kan míràn.
Abiola Olowe
Ìbàdàn
Leave a Reply