Take a fresh look at your lifestyle.

Sunak bẹ̀bẹ̀ ìrànlọ́wọ́ fun Gaza lásìkò àbẹ̀wò sí Egypt

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 269

Rishi Sunak ti ṣe ìpàdé pẹ̀lú ìjọba ààrẹ Palestine ní Egypt, lẹ́yìí tí ó jẹ́ ara àbẹ̀wò rẹ̀ sí Middle East.

Ọgbẹni Sunak ati Mahmoud Abbas jọ panupọ bẹnu atẹ lu bi Hama ṣe kọlu Israel ati PM ti o si ṣe ibanikẹdun ” fun iku awọn ara ilu ni Gaza.

O tun ṣe ipade pẹlu aarẹ orilẹ-ede Egypt Abdul Fattah al-Sisi, ti o si faramọ iyẹra funitankalẹ rogbodiyan”.

PM wa pe fun ṣiṣi ni kiakia bode Egypt-Gaza, nibi ti ogun awọn ọkọ akẹru iranlọwọ yoo gba wọle.

Ni kukuru ijiroro to waye laarin Ọgbẹni Sunak ati Ọgbẹni Abbas, da lori bibẹnu atẹ lu jagidijagan Hama ti o si tun ṣalaye pe Hamas ko ṣe nnkan ti awọn eniyan Palestine fara mọ”.

“Adari naa wa n pinnu lati nawọ iranlọwọ rẹ si Gaza, lati mu idaamu awọn ẹgbẹrun eniyan to n wa ounjẹ, omi ati oogun kuro,” alaye naa fi kun un.

Ọgbẹni Abbas ni o jẹ adari ijọba Palestine, ti o si ni ikapa lori awọn agbegbe West Bank, ṣugbọn kii ṣe ti Hamas tí Gaza wà lábẹ́ rẹ̀.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button