Lára akitiyan láti fi òpin sí ṣíṣe ìgbọ̀nsẹ̀ sí ìta gbangba, Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti pinnu ìjìyà fún ẹni yìówù tó bá ṣe igbọnsẹ tàbí tó bá da idọti sí ìta gbangba ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Komisana fún Ìròyìn àti Ìlanilọ́yẹ, Dọtun Oyelade ló sọ ọ̀rọ̀ yìí ni ìlú Ìbàdàn lásìkò ìpàdé ọlọjọ méjì pẹ̀lú àwọn oníròyìn, eleyii ti Àjọ UNICEF se àgbékalẹ̀ rẹ̀ lórí fífi òpin sí ìgbọ̀nsẹ̀ ni ìta gbangba ni àwọn Ìpínlẹ̀ Iwọ Oòrùn.
Kọmísánnà fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, Gómìnà Seyi Makinde ti paá laṣẹ fún Ilé iṣẹ́ to n rí sí ètò Ìdájọ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti fi ọwọ́ sìnkún òfin mu gbogbo ẹni yìówù tó bá tápà sí òfin tó lòdì sí ṣíṣe ìgbọ̀nsẹ̀ ni ìta gbangba.
O fi kún àlàyé rẹ̀ nígbà tó sọ di mímọ̀ pé, ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ṣetán láti ṣiṣẹ́ ni iṣọkan pẹ̀lú Àjọ UNICEF nípa titẹle àlàkalẹ̀ ọwọ́ fífọ̀ àti ìmọ́tótó eléyìí tí wọn pe ní ‘WASH’ (Water, Sanitation, and Hygiene)láti rí dájú pé ayípadà wà ko tó di ọdún 2027
O wá fi àsìkò náà rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí gbogbo olùgbé Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti tẹ̀lé òfin tó rọ mọ ìmọ́tótó.
Ṣáájú ní ẹni tó ṣe kòkáárí ètò ‘WASH’ ti Àjọ UNICEF, Monday Johnson sọ di mímọ̀ pé, iṣẹ́ ìwádìí Ilé iṣẹ́ tó nṣe Ìṣirò (National Bureau of Statistics) fi hàn pé Mílíọ̀nù Mejidinlaadọta (48 million) ọmọ Orilẹ èdè Nàìjíríà lo nṣe ìgbọ̀nsẹ̀ ní ìta gbangba.
Ọgbẹni Johnson fi kún àlàyé rẹ̀ nígbà tó sọ pé ṣíṣe Igbọnsẹ, yálà ní inú odò, inú igbó, tàbí gbogbo ibí tó fara pẹ náà ló túmọ sí ṣíṣe ìgbọ̀nsẹ̀ ní ìta gbangba, eléyìí tó wọpọ ni Orilẹ èdè Nàìjíríà.
Johnson wà jẹ kó di mímọ̀ pé Àjọ UNICEF ti ṣetán láti fi opin sí ìwà ìbàjẹ́ yìí ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Abiola Olowe
Ìbàdàn
Leave a Reply