Ilé-iṣẹ́ tí ń mójútó Ọkọ̀ ojú Irin ní Nàìjíríà, (NRC) ti kọ ìjábọ̀ tí ó sọ pé wọ́n fẹ́ jí àwọn ọkọ̀ ojú irin gbé ní Maiduguri, ìpínlẹ̀ Borno.
Ọgbẹni Fidet Okhiria, Alakoso Olùdarí ile-iṣẹ naa ni o sọ eyi ni ipinlẹ Eko.
“Ilé-iṣẹ́ tí ń mójútó Ọkọ̀ ojú Irin ní Nàìjíríà ti ṣe akiyesi si iroyin to n lọ kaakiri lori ẹrọ ayelujara, ti o wa lati Ile-Isẹ Mohun maworan orilẹ-ede Naijiria (NTA), eyi ti o ni wọ́n fẹ́ jí àwọn ọkọ̀ ojú irin gbé ní NRC Maiduguri.
“Iṣakoso NRC wa fẹ ko ye gbogbo eniyan pe aṣiṣe ni iroyin yii o, wọn ko awọn ọkọ oju irin ti wọn n sọrọ nipa rẹ yii kuro ni agọ NRC ni Jos, Plateau fun atunṣe lati le pada maa ṣiṣẹ ni,” o sọ bayii.
Okhiria wa sọ pe NRC n gbiyanju lati tan ọkọ oju irin ti n gbero lọpọ jakejado orilẹ-
ede.
Leave a Reply