Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara, Àríwá Àringbùngbùn Nàìjíríà, ti túnbọ̀ fìdí ìpinnu rẹ̀ láti fìdí àjọṣepọ̀ ààrin rẹ̀ àti ilé-iṣẹ́ tó ń ṣe òfin òògùn lórílẹ̀-èdè (NDLEA), rinlẹ̀ si láti mú orísiríṣi lílo òògùn lọ́nà tí kò bófin mu kúrò ní ìpínlẹ̀ náà pátápátá.
Kọmiṣọna fun ijọba ibilẹ, ọrọ ijoye ati idagbasoke agbegbe, Abdullahi Abubakar Bata sọ eleyi di mimọ nigba ti o n gba Adari ile iṣẹ naa ti ipinlẹ, Mohammed Bashir Ibrahim lalejo ni ọfiisi rẹ fun abẹwo.
Bata sọ pe bi ilokulo oogun ṣe n pọ si laarin awọn ọdọ jẹ nnkan to kọ ijọba ipinlẹ lomi nu, ti o si sọ pe awọn ile-iṣẹ ijọba to nii ṣe pẹlu rẹ nilo lati wa ọna abayọ lori kikoju iwa aburu naa.
Kọmiṣọna wa sọ bi abẹwo naa ṣe bọ si asiko si, ti yoo si fun oun lanfaani ati jiroro ati lati wa ọgbọn ti yoo mu lilo oogun oloro yọ lọkan awọn ọdọ nipasẹ ji jẹ ki wọn mọ ewu to wa ninu aimale mara duro fun lilo oogun.
Leave a Reply