Owó Oṣù Òṣìṣẹ́ Fẹ̀yìntì: Ìjọba Fi Ọwọ Sí Sisan Igba Mílíọ̀nù Àti Mẹ́fà Náírà (N206m) Owó Òṣìṣẹ́ Fẹ̀yìntì
Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti fi ọwọ́ sí sisan igba Mílíọ̀nù àti Mẹ́fà Náírà (N206m) owó oṣù òṣìṣẹ́ fẹ̀yìntì, nígbà tó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Mejilelaadorun (92) òṣìṣẹ́ fẹ̀yìntì ni o rí owó gbà nínú owó tí ìjọba ti san sẹ́yìn.
Kọmísánnà fún Ìdásílẹ̀ àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ (Establishment and Training), Adeniyi Adebisi ló sọ èyí di mímọ̀ nínú àtẹ̀jáde tí Kọmísánnà fún Ìròyìn, Dọtun Oyelade fi síta, tó sì kìlọ̀ fún àwọn òṣìṣẹ́ fẹ̀yìntì láti ṣọra fún àwọn oníjìbìtì ẹ̀dá to n ṣèlérí fún wọn pé owó ìfẹ̀yìntì wọn yóò jẹ sisan ní kíákíá.
Adeniyi wá tẹnu mọ pé, gbogbo òṣìṣẹ́ fẹ̀yìntì tó bá fẹ́ ṣe ètò bi yóò ṣe máa gba owó ìfẹ̀yìntì rẹ̀ lati wá sí ilé iṣẹ́ Ìjọba tààrà ki wọn má baà bọ sí panpẹ àwọn oníjìbìtì.
Bákan náà ni Kọmísánnà jẹ́ kó di mímọ̀ pé ìṣèjọba Gómìnà Seyi Makinde kò ní fi ààyè gba ẹnikẹni tó bá lù èèyàn ni jibiti owó nitori irú ẹni bẹẹ yóò fi ojú wí iná òfin.
Ẹni tíì ṣe Akọwe ẹ̀ka ilé iṣẹ ìjọba náà, Olajide Okesade rọ àwọn òṣìṣẹ́ fẹ̀yìntì láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti ṣe iṣẹ́ wọn.
Okedare náà tun tẹnu mọ pé ilẹ̀kùn ilé iṣẹ Ìjọba wà ní ṣíṣí fún gbogbo ẹni yìówù tó bá ní ìbéèrè, o wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, ilé iṣẹ ìjọba náà tí gùn lé wíwá ọ̀nà tí yòó rọrùn fún òṣìṣẹ́ fẹ̀yìntì láti máa gba owó wọn.
Abiola Olowe
Ìbàdàn
Leave a Reply