Ní ìgbìyànjú láti kojú àwọn ìṣòro gbígbé èpò wọlé àti ipá rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ owó paṣipaarọ pẹ̀lú owó ilẹ̀ òkèèrè tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà bí ìjọba ṣé tún èrò rẹ̀ pàá láti tún àwọn ilé ìfọpó orílẹ̀-èdè náà ṣé.
Mínísítà Ìpínlẹ̀ fún ilé-iṣẹ́ ọ̀rọ̀ Èpò, Sẹnetọ Heineken Lokpobiri ló sọ èyí di mímọ̀ lásìkò àbẹwò tí ẹgbẹ́ àwọn onílé ìṣẹ́ ìfọpó rọbi tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (CORAN), tí alága wọ́n, Momoh Oyarekhua ṣé nílu Abuja.

Nínú àtẹ̀jáde kàn tí ìgbákejì Olùdarí ètò ìròyìn gbogbogbò tí Ilé-iṣẹ́ èpò rọbi, Oluwakemi Ogunmakinwa, fí lédè ní Abuja.
Mínísítà náà sọ fún àwọn aṣojú náà pé Ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò tẹ̀síwájú láti máa ṣé àjọṣepọ̀ pẹ̀lú wọ́n láti wá ojútùú sí àwọn ìṣòro tó ń kojú wọ́n.
Ó sọ pé Ilé-iṣẹ́ tí Ọrọ̀ Èpò rọbi yóò ṣé àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ilé-iṣẹ́ mìíràn tó yẹ, , bí ilé-iṣé ètò ìnáwó tí ìjọba àpapọ̀ àti bánkì àpapọ̀ tí orílẹ̀-èdè náà lórí ètò ẹyà’wo lọ́nà tó rọrùn.

Ṣáájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, alága ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ olówó epo rọbi ti ilẹ̀ Nàìjíríà (CORAN), Ọ̀gbẹ́ni Momoh Oyarekhua sọ pé wọ́n dá ẹgbẹ́ náà sílẹ̀ láti ṣé àtúnṣe iṣẹ́ èpò rọbi ní Nàìjíríà àti láti gbé orílẹ̀-èdè náà sí ojú ọ̀nà ìmújáde abẹ́lé.
Leave a Reply