Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn ènìyàn tó lé lẹ́gbẹ̀rún mẹ́jọ yóò péjọ fún IGF ní Japan

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 204

Àwọn ènìyàn tó lé lẹ́gbẹ̀rún mẹ́jọ jákèjádò àgbáyé ti ṣetán àti kórajọ fún Àpèjọ Ìṣàkóso Ayélujára (IGF), ẹlẹ́ẹ̀kejìdín-lógún ní Kyoto, orílẹ̀-èdè Japan, láti ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹwàá sí ọjọ́ kejìlá, 2023.
Àpèjọ pataki yii, ti akọle rẹ jẹ “Ayelujara ti a fẹ – Riro gbogbo eniyan lagbara,” ti wọn ṣagbekalẹ rẹ lati yanju awọn ipeninija ati anfaani ti o n waye nipasẹ ayeluja ti n gbooro si niṣẹju iṣẹju.
Ijiroro naa da lori lilo alaye lasiko ayelujara tuntun ati lati ko anfaani imọ ẹrọ lọpọ fun imudara agbegbe ati agbaye.
Ọkan pataki lara ohun to jẹ IGF logun ni ipin ayelujara, pẹlu bi awọn eniyan to le ni Miliọnu meji lagbaye ko ṣe tun ri lilo ayelujara larọwọto wọn, paapaa julọ ni Gusu agbaye ati agbegbe ti o le ní ipalara.Apejọ naa yoo tun sọrọ lori ipa ayelujara lori gbogbo agbegbe, pẹlu awọn ti wọn n ri lo ati awọn ti ko rii lo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button