Take a fresh look at your lifestyle.

Aṣòfin ìpínlẹ̀ Abia gbóríyìn fún ìdájọ́ ilé ẹjọ́ ìdìbò

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 215

Ọmọ ilé ìgbìmọ̀ Aṣojú tí ń ṣojú agbègbè Arochukwu/Ohafia ti ìpínlẹ̀ Abia, Ibe Osonwa (LP) ti kí Gómìnà Alex Otti ti Abia kú oríire lórí àṣeyege ní ilé ẹjọ́ ìdìbò.

Osonwa sọ pe idajọ naa fi ifẹ inu gbogbo eniyan  Abia ti o dibo fun gomina han ninu idibo gbogbogboo to kọja.

O sọ pe ababọ ile ẹjọ naa tunbọ wa fidi esi lati ọpọlọpọ ibudo idibo, agbegbe ati awọn ijọba ibilẹ Abia han gbangba.

Osonwa wa rọ olupẹjọ lati yọnu si Otti ki wọn o si jẹ ki ifẹ awọn eniyan Abia wa lookan aya wọn, ki wọn o le ko ipa tiwọn lati wa ọkọ ipinlẹ naa siwaju.

Ile ejọ ti n gbọ awuyewuye eyin ibo ti ipinlẹ  Abia ti o wa ni Umuahia, ni ọjọ Ẹti, ti fidi ikede  Otti gẹgẹ bii ẹni ti o jawe olubori ninu idibo gomina ọjọ kejidin-logun, oṣu kẹta ni Abia.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button