Ọ̀RỌ̀ ÀÀRẸ TINUBU LÓNÌÍ ỌJỌ́ AYẸYẸ ÀYÁJỌ́ ỌDÚN ÒMÌNIRA LÓRÍLẸ̀DÈ NÀÍJÍRÍÀ
George Ọláyínká Akíntọ́lá
Ẹ̀yin Ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàíjíríà,
Pẹ̀lú ìdùnnú ọkàn ní mo fi n ba yin sọrọ lónìí ọjọ́ kinni, oṣu kẹwàá, Ọdun 2023, Ọjọ́ ayẹyẹ ọdún òmìnira ti Orílẹ̀-èdè Nàíjíríà pé Ọdún Mẹ́tàlélọ́gọ́ta gẹ́gẹ́ bíi Ààrẹ àti ọmọ Ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàíjíríà
Ẹ jẹ ka gboriyin fún àwọn Baba àti Iya wa to bẹrẹ irinajo. Láì sí wọn, ko ni si oun tó ń jẹ́ Orílẹ̀-èdè Nàíjíríà tí a mọ̀ lónìí. Ìlàkàkà àti ìgbìyànjú wọn láti ìgbà tí wọ́n ti kó wa lẹ́rú, ló jẹ́ kí á di Orílẹ̀-èdè to daduro ti o si gba ominira
Ní àkókò yìí, ẹ jẹ ki a gbagbọ pé gẹgẹ bi ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàíjíríà, gbogbo wa la ni ẹbun kan àti omiran, ti Ọlọrun fi jìnkí Orílẹ̀-èdè Nàíjíríà gẹgẹ bi Orílẹ̀-èdè àti ọmọnìyàn. Ko si ẹni to ju ẹnìkankan lọ, bákan náà ni wá. Gbogbo oun ta ti lakọja yoo fún wa ni okun si, ko ni si Orílẹ̀-èdè kankan ní ayé yìí ti yoo di wa lọwọ láti ni anfaani sí oun tó tọ́ sí wa. Ti wa ni Orílẹ̀-èdè yìí, ẹ nifẹ rẹ̀ gẹgẹ bi tiyín
Orílẹ̀-èdè Nàíjíríà jẹ, èyí tó tóbi gidi pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà oriṣiriṣi, ẹ̀sìn, àṣà, àti ìṣe, o kun to so wá pọ nípọn gan, ko ṣe foju ri, o si kaakiri àgbáyé. À ń pòngbẹ fún oun kan náà, àlàáfíà, ìlọsíwájú, aṣeyọri, iṣọkan, itẹlọrun àti idajọ to yẹ koro.
Mo ṣe àwọn ìlẹ́rí to yanranti lori bí ma ṣe ṣe Ijọba lọjọ ti mo di Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàíjíríà, Lára àwọn ileri yìí ni pé, màá tún àwọn ibi to nilo atunṣe se, èto ọrọ̀ ajé wa yo ní idagbasoke, maa si dábòbòò ẹ̀mí àwọn ará ìlú àti oun ìní wọn.
Mo sọ pé, àwọn ìgbésẹ̀ to lágbára kan pọn dandan láti leè jẹ́ kí Orílẹ̀-èdè Nàíjíríà daa si, ko si goke, Lori èyí ní mo ṣe ìkéde fífi òpin sí owó iranwọ epo rọ̀bì
Mo n gbọ́, mo n ri gbogbo oun ti o n lọ ni Orílẹ̀-èdè Nàíjíríà, mo si rọ yin pe, ki ẹ farada fún gba diẹ, gbogbo rẹ yoo bọ si po
Tinubu ni gbogbo nkan ni yoo pada dẹrọ pẹlu bi awọn eeyan ti n fara da ọwọngogo nkan lọja bayii.
Mo kéde ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n náírà lóṣooṣù gẹgẹ bi owo iranwọ fawọn oṣisẹ ijọba onipo kekeke.
Ààrẹ Tinubu sọ ninu ọrọ rẹ pe oun kede owo yii lati le ṣe iranwọ fawọn oṣiṣẹ ti owo oṣu wọn ko gbewọn to pẹlu bi gbogbo nkan ṣe gbowo lori lọja bayii.
Aarẹ Naijiria ni awọn oṣiṣẹ yii yoo jẹ anfaani owo naa fun oṣu mẹfa lati akoko yii lọ.
Bakan naa ni Tinubu sọ pe ijọba oun si n ṣiṣẹ lori afikun owo oṣu tuntun fawọn oṣisẹ ni Naijiria.
Aarẹ Tinubu tun ṣalaye pe ijọba oun ti pese awọn ọkọ ti yoo maa gbe awọn eeyan ni ẹdinwo kaakiri gbogbo ipinlẹ ni Naijiria pẹlu bi owo ọkọ ti di gọbọi bayii.
Tinubu wa rọ ọmọ Naijiria wi pe ki wọn tubọ ni ifarada sii wi pe didun ni ọsan yoo so laipẹ lai jina.
Ààrẹ Tinubu ṣeleri pe, oun ko ni ja àwọn ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàíjíríà kulẹ̀, a o jọ ṣe iṣẹ yii papọ ni, ti yoo fi dara.
Ààrẹ ki gbogbo wa ku ayẹyẹ Ọdún Mẹ́tàlélọ́gọ́ta ti a gba òmìnira
Ọlọ́run yóò bùkún fún Orílẹ̀-èdè Nàíjíríà
George Ọláyínká Akíntọ́lá
Leave a Reply