Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu Fi Kun Owó Oṣù Àwọn Òṣìṣẹ́

0 224

Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti Kéde àfikún owó oṣù àwọn Òṣìṣẹ́ pẹ̀lú èlé ẹgbẹ̀rún màrúndínlọ́gbọ̀n Náírà ní osoosù fún osù mẹ́fa tó ń bọ̀.

Ó sọ èyí níbi àyájọ́ ọjọ́ òmìnira Nàìjíríà tó pé ọmọ ọdún mẹ́tàlélọ́gọ̀ta ní ọjọ́ Àìkú, oṣù Kẹwàá, ọdún 2023

Ó fi kun pé èyí ri bẹ̀ látàrí ìfikùlukùn tó wáyé láàrin ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ àti ìjọba. Èyí ki sí ṣe láti jẹ́ kí ohun gbogbo gbé owó lóri ṣùgbọ́n kí ara le túbọ̀ dẹ àwọn òṣìṣẹ́.

Ó tún fi lede pé, àwọn ìpínlẹ̀ ti gba owó ìrànwọ́ láti ọ̀dọ̀ ìjọba láti pèsè nǹkan ìrẹmọlẹ́kún fún àwọn ènìyàn wọn ki ara le bà tu mùtúmùwà.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button