Ojogbon ti imo ẹjẹ ati gbigba rẹ ti Ifafiti Ètò Isegun Oyinbo, ìlú Eko, Sulaimon Akanmu ti so pe fifi eje sile, kí je ki ènìyàn darugbo Kíákíá, o n je ki emi gùn ni.
Akanmu sọ pé àwọn tó bá n fi ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ lóòrèkóòrè kìí ni isoro ti àìtó èròjà ‘Iron’ ma n da sí ara, ti o mú kí eniyan darugbo kíá, o fi kun pe fifi eje silẹ o kere tan ìgbà meji lọ́dún n je ki ènìyàn ni ilera pipe.
Ó wá rọ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti máa fi ẹjẹ silẹ nitori pe anfaani rẹ ko lẹ́gbẹ́ bi gbogbo àgbáyé se sọ.
Ó tun je ki opolopo máa lé e sọ èmí wọn nù, o je ki ẹ̀mí aláìsàn tó nilo ẹ̀jẹ̀ gun sí.
Akanmu sọ pe fifi ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ni orílẹ̀-èdè to ti gòkè àgbà, awọn to n fi ẹ̀jẹ̀ sile n ṣee lọfẹ, èyí ni àjọ World Health Organisation n fẹ́, ti won sì lọ́wọ́ sí.
Ọ̀jọ̀gbọ́n pariwo sita àìtó ẹjẹ ti orile-ede yii nilo fún àwọn ènìyàn rẹ tó jìnnà pátápátá sí nnkan ti àjọ WHO n fẹ́.
Àjọ WHO kanpa pé enikan ninu ọgọ́rùn ènìyàn nilati tabi ko wù láti fi eje silẹ.
Ọjọ̀gbọ́n to gba awọn mọ̀lẹ́bí ti wọ́n nilò ẹ̀jẹ̀ fifi sile tabi gbigba sọ pé kí wọn máse lọ sí ilé iṣẹ iwosan aládáni, o kìlọ pé àwọn ẹjẹ ti won fi sile ni ti aládáni máa n ni awọn arun kan nínú.
Àjọ WHO sọ pé ẹjẹ fifi silẹ n ra emi pada, o n fa ilera pipe botile je pe àwọn to nilò rẹ̀ wọn ki ri ẹ̀jẹ̀ náà gbà ni àsìkò.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply