Take a fresh look at your lifestyle.

Eid-el Maulud: Makinde Pé Musulumi Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Fún Àdúrà Àti Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Wọn

0 240

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti pe gbogbo Mùsùlùmí láti tẹ síwájú nínú adura àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ fún àwọn adarí Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Makinde, nínú àtẹ̀jáde tí Akọwe ìròyìn rẹ̀, Suleiman Olarewaju fi síta ló sọ ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó n kí àwọn ẹlẹṣin Islam jákèjádò Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti ní tibi tòòró Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kú ayẹyẹ Ọdún Eid-el Maulud (Rabi’ al-Awwal ìkejìlá) ti ọdún 2023, eléyìí tó n ṣàmì ọjọ ìbí Òjíṣẹ Nla Muhammad (S.A.W).

Makinde, ẹni tó gba gbogbo Mùsùlùmí níyànjú láti lò àsìkò ìrántí ọjọ́ ìbí Òjíṣẹ Nla náà láti wá ojú Allah fún Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti Orilẹ èdè Nàìjíríà lápapọ̀, o wá fi àsìkò náà lù won lọgọ ẹnu fún ìkúnlọ́wọ́ wọn nínú ìṣèjọba rẹ̀.

Makinde fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ìṣèjọba oun bu ọlá fún ìkúnlọ́wọ́ àti ádùrá Mùsùlùmí Ummah ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, nígbà tó tẹnu mọ pé òun n rí ẹ̀rí ádùrá wọn.

O wá ki gbogbo wọn kú ewu ọdún Eil-el Maulud.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button