Take a fresh look at your lifestyle.

Nàìjíríà Yòó Ṣé Àtilẹ́yìn Ìbáṣépọ̀ Àgbáyé Fún Ètò Ẹ̀kọ́

0 336

Mìnísítà Ìpínlẹ̀ fún ètò Ẹ̀kọ́, Dókítà Yusuf Sununu, sọ pé Ìjọba tí ṣétan láti ṣé àtilẹ́yìn Ajọṣépọ̀ Àgbáyé Fún Ẹ̀kọ́, GPE, látí ṣé àṣéyọrí ìdágbàsóké ní ẹ̀ká nàá.

Sununu sọ èyí ní ilé-iṣẹ́ rẹ̀ ní Abuja Nígbà tó padé pẹ̀lú àwọn òṣíṣẹ́ GPE tí ọgá àgbá nípa ètò ẹ̀kọ́ àti àlákósó Orílẹ̀-édé, Morten Sisgaard ọmọ Orílẹ̀-èdè Denmark.

Ninu alaye ti Oludari Atẹjade si Minisita Ben Goong sọ, Sununu ṣe ileri pe Ijọba Bola Ahmed Tinubu ni ifẹ lati ṣe daada ni gbogbo ẹka.

Olori Aṣoju naa, Morten Sisgaard sọ fun Minisita pe GPE ni awọn eto pataki ni Nigeria, pẹlu iṣẹ akanṣe ọlọgọrun miliọnu ($100M) lati 2015 – 2020. Eyi ni ero lati ni ilọsiwaju to dara ni eto Ẹkọ ipinlẹ ni Kastina, Kano, Kaduna, Jigawa ati Sokoto.

Lara awọn toṣé abẹwo naa pẹlu Morten Sigsaard, ni Oludamọran Ẹkọ Agba ni Ile-iṣẹ giga ti Ilu Gẹẹsi ni Abuja, Ọgbẹni Ian Attfield, ati Dilip Parajuli, Onimọ-ọrọ-aje agba ati Alamọja Ẹkọ ni Banki Agbaye.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button