Take a fresh look at your lifestyle.

NUJ pè fún ìṣèwáádí ikú tó pa akọ̀ròyìn VON

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 326

Ẹgbẹ́ àwọn Akọ̀ròyìn ti Ikọ̀ ìpínlẹ̀  Zamfara  (NUJ), ti pe àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìdìbò láti ṣe ìwáádí tó dáńgáájíá sí ikú tó pa àgbà akọ̀ròyìn tí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Voice of Nigeria (VON), Hamisu Danjigba.

Ninu ọrọ kan ti akọwe ẹgbẹ naa, Ibrahim Ahmed, buwọlu sọ pe awọn ti wọn furasi bii ajinigbe lo ji oloogbe Danjibga gbe ti wọn si rii ninu ile idagbọnsẹ si lẹyinkule ile rẹ, lẹyin ọjọ kẹtaa.

 “Oorun ti ko dara ti awọn ọmọ ile Keu n gbọ ni Ọjọọru, ogunjọ, oṣu kẹsan an 2023, ni wọn pe akiyesi olukọ wọn si ti wọn fi ri oku Akọroyin naa.

 “Lẹyin ti wọn fọ ile idagbẹsi naa ni awọn ẹbi ati aladugbo Danjibga ri oku rẹ.Wọn si ti ṣe eto isinku rẹ gẹgẹ bii ti awọn ẹlẹsin Musulumi.

 “ Ẹgbẹ naa wa ṣedaro pẹlu ẹbi, Voice of Nigeria ati gbogbo ipinlẹ Zamfara.

Bi iku Danjibga ṣe ka ẹgbẹ naa lara to, o wa rọ awọn osiṣẹ eleto aabo lati ṣe iwaadi gidi si idi iku naa ati ki wọn si da ẹjọ to yẹ fun ẹni to wu iru iwa buburu bẹẹ,” alaye naa lọ bayii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button