Ilé iṣẹ́ ààrẹ ṣe ayẹyẹ ọjọ́ọ́bí ọdún kẹtàlé-lọ́gọ́ta pẹ̀lú arábìnrin àkọ́kọ́ Nàìjíríà Ilé
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ilé iṣẹ́ ààrẹ ti ṣe ayẹyẹ ọjọ́ọ́bí ọdún kẹtàlé-lọ́gọ́ta pẹ̀lú arábìnrin àkọ́kọ́ Nàìjíríà, Sẹ́nétọ̀ Ìyáàfin Olurẹmi Tinubu, CON, OON.
Ninu alaye kan ti oludamọran pataki fun aarẹ lori eto ibaraẹnisọrọ ati ipolongo, Oloye Ajuri Ngelale, sọ pe awọn olusakoso ile ilu ati oṣiṣẹ ṣajọyọ pẹlu Sẹnetọ Olurẹmi Tinubu, pe o jẹ arábìnrin àkọ́kọ́ orile-ede Nàìjíríà nikan kọ ṣugbọn gẹgẹ bi iya to nifẹẹ, ti o si n gbọ ti awọn ọmọ rẹ ati ti gbogbo orile-ede.
Ngelale wa ṣapejuwe iwa rere Sẹnetọ Tinubu ti i si sọ pe o tayọ ipo rẹ gẹgẹ bii alatilẹyin pataki ati olufọkantan ọmọ orilẹ-ede Naijiria akọkọ.
Agbẹnusọ aarẹ naa wa tun ṣapejuwe arábìnrin àkọ́kọ́ bii adari to kunju osunwọn, olukọni, Alaanu, ati olujiṣẹ ọlọrun to duro ṣinṣin.
Ngelale sọ pe Iṣẹ Akanṣe pataki Iyaafin Tinubu, ti o jẹ Eto Atunṣe Ireti (RHI), ti mu ireti ti o si tun ti tun aye awọn ọpọlọpọ ti wọn ti fipa si nipo ṣe ati awọn alaini ni Naijiria.
Leave a Reply