Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Akọ̀ròyìn Congo pè fún ìdásílẹ̀ òṣìṣẹ́, Stanis Bujakera

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 247

Àwọn Akọ̀ròyìn orílẹ̀-èdè Congo ti fún ilé iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ tí ń mójútó ìdájọ́, ní ìwé àdéhùn fún ìbéèrè láti dá alájọṣiṣẹ́ wọn, Stanis Bujakera sílẹ̀.

Wọn mu akọroyin Ọdọ Adulawọ ati ti wọn si ti mọle ni ọjọ kẹjọ, oṣu kẹsan an, lori ifurasi pe o tan ọrọ ti ko jootọ nipa pipa oloṣelu alatako pataki kan ni Kinshasa, ni oṣu keje.

Wọn ko darukọ Bujakera gẹgẹ bi ẹni ti o kọ iṣẹlẹ naa, leyi ti wọn tẹ jade lori ayelujara Ọdọ Adulawọ.

O kan sọrọ lori ijabọ kan lati ile iṣẹ ọgbọn orilẹ-ede lori iru iku to pa Minisita tẹlẹ ri naa Chérubin Okende.

Ijọba Congo ni ko so otitọ kankan ninu ijabọ naa, ti o si ṣapejuwe rẹ bii ọrọ Ahesọ ti wọn fẹ fi ba ijọba loju jẹ”.

Edmund Izuba, agbẹnusọ fun ẹgbẹ awọn akọroyin, Rajec,ti o ṣe akojọ ifẹhonuhan naa, sọ pe Bujakera ko ṣe nkankan ti ko dara ti atimọle rẹ si jẹ “aitọna”.

Ẹgbe naa wa sọ pe ijọba n gbiyanju lati pa awọn akọroyin lẹnu mọ ni bi idibo ṣe n bọ lọna ni oṣu kejila yii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button