Take a fresh look at your lifestyle.

Nàìjíríà ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìgbìmọ̀ ìṣètò Àyájọ́ òmìnira ẹlẹ́ẹ̀kẹtàlé-lọ́gọ́ta

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 203

Ìjọba Nàìjíríà ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìgbìmọ̀ ìṣètò elénìyàn mẹ́ẹ̀dógún fún ayẹyẹ ọdún Àyájọ́ òmìnira ẹlẹ́ẹ̀kẹtàlé-lọ́gọ́ta oriĺẹ̀-èdè.

Akọwe fun Ijọba apapọ (SGF), George Akume ṣalaye pe ayẹyẹ naa yoo fun wọn lanfaani lati ṣafihan awọn aṣeyege ti ijọba ti ṣe lori ọpọlọpọ ipeninija ni abala ibaraeniṣepọ ati ọrọ-aje ti o n koju orilẹ-ede, laipẹ ki wọn to ṣe ifilọlẹ igbimọ naa.

SGF tun wa ṣalaye fun awọn igbimọ naa pe ki wọn maa jafara lori igbaradi fun ayẹyẹ ọhun.

Awọn ọmọ ẹgbẹ igbimọ naa ni: Minisita fun eto ibaraẹnisọrọ ati Aṣa; Minisita fun ọrọ orilẹ-ede, Minisita fun eto inawo ati iṣakoso, Minisita fun Ọrọ-Aje ati Minisita fun ọrọ okeere, Minisita fun olu ilu, Oludamọran lori eto aabo lapapọ, Aga agba fun awọn Agbofinro, Adari gbogbogboo, Ikọ iṣẹ orilẹ-ede ati alakoso, awọn ọmọ ogun ẹṣọ, ati awọn miiran.

George Akume, akọwe fun ijọba apapọ ni alaga igbimọ naa.Awọn eto ti wọn ti la silẹ fun ayẹyẹ naa ni;

  1. Ibawọn oniroyin sọrọ lagbaaye, ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kẹsan an.
  2. Ifọrọjomitoro ọrọ ati idanilẹekọ fun gbogbogboo, ọjọ kejidin-lọgbọn, oṣu Ọwẹwẹ,
  3. Irun Jimọh, ọjọ kọkandin-lọgbọn, oṣu Ọwẹwẹ.
  4. Ọrọ aarẹ, ọjọ kinni, oṣu Ọwawa; Isin Sọọsi.
  5. Iyan bii ologun, ọjọ keji, oṣu Ọwawa.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button