Take a fresh look at your lifestyle.

FCTA, ìpínlẹ̀ Nasarawa yóò fọwọ́wẹwọ́ lórí ṣíṣe ojú irin, ojú ọ̀nà

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 315

Mínísítà fún olú ìlú (FCT), Agbẹjọ́rò Nyesom Wike, ti ṣàlàyé ìpinnu ìṣàkóso náà láti fọwọ́wẹwọ́ pẹ̀lú ìjọba ìpínlẹ̀ Nasarawa lórí ìdàgbàsókè ojú irin àti iṣẹ́ ojú ̀nà.

Mínísítà sọ eyi nigba ti gomina ipinlẹ Nasarawa , Abdullahi Sule ṣabẹwo si ni ọfiisi rẹ ní Abuja, ní ọjọ Ẹti.

Nigba ti o n fidi bi Nasarawa ṣe sunmọ olu ilu si, minisita wa tẹnumọ pataki ati fọwọsowọpọ fun idagbasoke awọn ilu mejeeji.

O sọ pe iṣakoso olu ilu yoo jumọ jiroro pẹlu ijọba Nasarawa lori idagbasoke oju Irin lati Apo si Keffi, ati pipari oju ọna Barakii Abacha si Masaka.

Gẹgẹ bi o ṣe sọ, Oju irin naa ṣe pataki ṣugbọn o wọn pupọ.

Owa fi kun un pe awọn ti gbaradi lori aṣẹ ti aarẹ Bọla Tinubu pa lati tun oju irin naa ṣe, ni eyi ti yoo pari laarin oṣu meje.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button