Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu yóò gbéra kúrò ní Abuja lọ fun UNGA78 ní ọjọ́ Àìkú

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 429

Ààrẹ Nàìjíríà, Bọla Ahmed Tinubu yóò gbéra kúrò ní Nàìjíríà ní ọjọ́ Àìkú lọ sí New York, Amẹrika fún ìpàdé àwọn adarí ọlọ́dọọdún, ti ilé ìgbìmọ̀ àpapọ̀ Àjọ Ìṣọ̀kan, UNGA78.

Akọle fun ti ẹlẹẹkejidin-lọgọrin ti yoo waye ni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ karun un, oṣu Ọwẹwẹ ni: Atunṣe igbagbọ ati ajinde iṣọkan agbaye: ṣiṣe iṣẹ kiakia lori ipinnu  2030 ati idagbasoke erongba ibiafẹde lori alaaafia, ilọsiwaju, idagbasoke ati ibiafẹde fun gbogbogboo

Nigba ti o n ba awọn akọroyin ile ilu sọrọ lori irinajo aarẹ ati ohun to wa lọkan rẹ lati ṣe ní  New York, oludamọran pataki rẹ lori eto ibaraẹnisọrọ ati ipolongo, Ajuri Ngelale sọ pe ohun to wa lookan aya aarẹ Tinubu nibi ariyanjiyan gbogbogboo naa ni lati ṣe igbelarugẹ ọrọ aje Naijiria.

Ngelale wa tẹnumọ pe adari Naijiria yoo ṣe ipade lọna meji lori ariyanjiyan awọn adari lagbaye pẹlu aarẹ orilẹ-ede Amẹrika, Comoros, South Africa, aarẹ igbimọ Ajọ Iṣọkan Yuroopu, adari orile-ede Netherlands, Ọba orile-ede Jordan ati aarẹ orilẹ-ede.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button