Ààrẹ Nàìjíríà gb́e ìgbìmọ̀ tí yóò pẹ̀tù sí aáwọ̀ ààrin àwọn adaran àti àgbẹ̀ dìde
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ààrẹ Nàìjíríà, Bọla Ahmed Tinubu ti buwọ́lu ìdásílẹ̀ ìgbìmọ̀ ààrẹ tí yóò gbé ìmọ̀ràn sílẹ̀ fún ìpèsè ìgbépapọ̀ àlàáfíà láàrin àwọn Adaran àti Àgbẹ̀, tí yóò sì tún rí sí ìpèsè ààbò àti ìwà lálàáfíà ọrọ̀-ajé gbogbo ọmọ Nàìjíríà.
Ààrẹ Nàìjíríà sọ pe igbimọ yoo tun ri si atunṣe ile-iṣẹ ẹka Ọsin ti yoo si wa atunṣe ti yoo pẹ si ija aiyede to maa n waye laarin awọn agbẹ ati adaran loorekoore ní orilẹ-ede.
Ààrẹ kede idasilẹ igbimọ naa ninu ọrọ kan ti oludamọran pataki rẹ lori eto ibaraẹnisọrọ ati ipolongo, Ajuri Ngelale buwọlu, lẹyin ijabọ lati ibi ipade atunṣe lori ohun ọsin lorilẹ-ede ati atunṣe awọn lori ede aiyede to fara pẹẹ ni Naijiria.


Gomina ipinlẹ Kano ti o tun jẹ alaga fun ẹgbẹ All Progressives Congress (APC), Dokita Umar Abdullahi Ganduje, ni o po apejọ naa.
Leave a Reply