Take a fresh look at your lifestyle.

Igbákejì ààrẹ Shettima yóò ṣàbẹ̀wò sí ìpínlẹ̀ Kebbi, Sokoto

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 208

Igbákejì ààrẹ Naijiria, Kashim Shettima yóò ṣe àbẹ̀wò sí ìpínlẹ̀ Kebbi àti Sokoto ní Gúsù iwọ̀ oòrùn Nàìjíríà.

Ní ipinlẹ Kebbi , Igbákejì ààrẹ yóò ṣe abẹwo ibanikẹdun si ẹbi oloogbe Alufa, Sheikh Abubakar Giro ní Argungu.

Sheikh Giro, ti o di oloogbe ni Ọjọọru, jẹ onimọ ẹsin Musulumi ti o si tun jẹ Akọwe alakoso ẹgbẹ Jama’atul Bidi’a Wa’ikamatul Sunnah (JIBWIS), ki o to di oloogbe.

 

Àwọn oṣiṣẹ eleto aabo ti wa ni ile oloogbe onimọ ẹsin Islam naa ati ni aafin Emir ti Argungu, ni igbaradi fun abẹwo Igbákejì ààrẹ.

Igbákejì ààrẹ Shettima yoo wa lọ si ipinlẹ Sokoto, lẹyin eyi fun ifilọlẹ awọn isẹ Akanṣe Gomina ipinlẹ naa, lati ṣami ọgọruun ọjọ tí gomina ipinlẹ naa, Ahmed Aliyu, gori oye ni ọjọ kọkandin-lọgbọn, oṣu karun, 2023.

Igbákejì ààrẹ yoo tẹsiwaju lori ifilọlẹ awọn isẹ Akanṣe  Sokoto ní ọjọ́ Aje, ki o to pada si  Abuja.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button