Take a fresh look at your lifestyle.

Igbákejì ààrẹ Shettima ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìpàdé ìgbìmọ̀ gómìnà Aríwá ilà oòrùn ẹlẹ́ẹ̀kẹjọ

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 217

Igbákejì ààrẹ Naijiria, Kashim Shettima ti ṣíṣọ lójú ìpàdé ìgbìmọ̀ gómìnà Aríwá ilà oòrùn ẹlẹ́ẹ̀kẹjọ ní Maiduguri, olú ìlú ìpínlẹ̀ Borno, Aríwá ilà oòrùn Nàìjíríà.  Shettima  ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìpàdé náà lásìkò tó ṣe àbẹ̀wò sí ìpínlẹ̀ Borno láti ṣí àwọn iṣẹ́ Àkànṣe tí Gómìná Babagana Zulum ṣe láàrin ọgọ́rùún ọjọ́ tí ó ti lò nínú sáà rẹ̀.

O wa gboriyin fun awọn Gomina Aríwá ilà oòrùn fun iṣeraẹnilọkan biotilẹjepe wọn oṣelu ti onikalukuu wọn n ṣe ti o si rọ wọn ki wọn fọwọsowọpọ fun idagbasoke Ẹkùn wọn.

Ọjọgbọn Babagana Zulum, tí ó jẹ́ Gomina ipinlẹ Borno tí ó sì tún jẹ́ alaga igbimọ Aríwá ilà oòrùn, tun wa gboriyin fun aṣeyege ọmọ ologun Naijiria lori kikoju awọn oni jagidijagan. O sọ pe awọn mọ rírì akitiyan wọn, ti ijagbara wọn si fojuhan gbangba.

Gomina Zulum tun wa ṣe sadankata fun awọn Gómìnà Aríwá ilà oòrùn fun  ipinnu ati iṣewadi lati mọ ati lati wa atunṣe si awọn ipeninija ti n koju Ẹkun naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button